Peter ti dero ẹwọn o, orukọ oyinbo Amẹrika lo fi lu jibiti n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Adajọ Abdulgafar, tile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti sọ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Ayẹni Peter Oluwatofunmi, sẹwọn oṣu mẹfa, fẹsun fifi orukọ obinrin oyinbo ilẹ Amẹrika kan lu jibiti.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni adajọ ni ki afurasi ọdaran naa lọọ ṣẹwọn osu mẹfa fẹsun pe o n lo orukọ oyinbo ilẹ Amẹrika kan Daina Patrick, to si fi n lu awọn eniyan ni jibiti.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku EFCC, lo wọ Peter lọ siwaju Onidaajọ Mahmoud Abdulgafar, fẹsun pe o n forukọ ọmọ bibi ilẹ Amẹrika kan, Arabinrin Daina Patrick, lu jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Rashidat Alao to jẹ asoju ajọ EFCC lo mu ẹlẹri lọ siwaju ile-ẹjọ  lati fidi otitọ mulẹ. Olujẹjọ naa gba pe loootọ lo jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan an.

Onidaajọ Abdulgafar ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri ti olupẹjọ ko siwaju ile-ẹjọ, o han pe loootọ ni olujẹjọ naa jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan an, fun idi eyi, ki Peter lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara, bakan naa ladajọ tun ni ki gbogbo awọn dukia to ko jọ lọna eru di tijọba apapọ ati owo ti wọn ba lọwọ rẹ igba dọla owo ilẹ okeere ko di tijọba.

 

Leave a Reply