Peter ti dero kootu o, agolo ẹwa mẹwaa ati miliiki mẹrin lo ji l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alex Peter, ẹni ogun ọdun, ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lori ẹsun ole jija.

Inu Oroki Housing Extension, niluu Oṣogbo, ni ọwọ ti tẹ Peter laago marun-un irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta oṣu ti a wa yii.
Gẹgẹ bi agbefọba, Abiọdun Fagboyinbo, ṣe sọ fun kootu, agolo miliiki mẹrin, agolo ẹwa mẹwaa, ọra spagẹti mẹfa, ọra maggi kan ati baagi sẹmofita kan ni olujẹjọ ji ni sọọbu Ronkẹ Adeṣiyan, apapọ owo wọn si jẹ ẹgbẹrun meje o din igba Naira.
Fagboyinbo ni iwa ti olujẹjọ hu naa ni ijiya labẹ abala okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.
Ninu awijare rẹ, Peter ṣalaye pe lati ilu Ọrẹ, nipinlẹ Ondo, loun ti wa anti oun kan wa si Oṣogbo, ṣugbọn gbogbo igbiyanju oun lati ba a sọrọ lori foonu lo ja si pabo, nitori foonu rẹ ti ku, bẹẹ oun ko mọ adirẹẹsi ile to n gbe.
O ni loootọ loun lọ si ṣọọbu naa nitori ebi to n pa oun, oun si ba awọn ọmọ kekeke nibẹ, ṣugbọn oun ko ji awọn nnkan jijẹ naa.
Arabinrin Ronkẹ to ni ṣọọbu sọ pe ṣe ni Peter sọ pe oun fẹẹ ra gbogbo awọn nnkan to ko, ṣugbọn bi wọn ṣe di i sinu ọra fun un lo bẹrẹ si i sa lọ.
Lẹyin ti olupẹjọ rojọ tan lo rọ kootu lati da olujẹjọ silẹ, ko maa lọ lalaafia.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ A. Adeyẹba fagi le ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ nitori oun ti olupẹjọ sọ, pẹlu ikilọ pe ko gbọdọ huwa aitọ mọ.

Leave a Reply