Adewale Adeoye
Ni bayii, inu ahamọ awọn agbofinro orileede Amẹrika, ni ọmọ Naijiria kan, Ọgbẹni Ahmed Kamilu Alex, ẹni ọdun marundinlogoji, tawọn ọlọpaa orileede naa ti n wa tipẹ wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n ṣẹ Yahoo Yahoo laarin ilu, ati pe ọpọ araalu naa lo ti lu ni jibiti owo nla ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lọwọ ikọ akanṣe ọlọpaa orileede Amẹrika tẹ ẹ lorileede Philippines, nibi to sa lọ, nitori ti wọn ti kede rẹ pe, wọn n wa a ni Amẹrika, f’ohun to ṣe.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Quezon, lorileede naa to sapamọ si lọwọ ti to o, ti wọn si ti fọwọ ofin mu un pada wa si Amẹrika, lati waa jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa FBI lorileede Amẹrika, Ọgbẹni Joel Anthony Viado, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, sọ pe latigba ti afurasi ọdaran naa ti gbọ pe awọn ọlọpaa orileede Amerika n wa a lo ti sa kuro ni Amerika lọ sọhun-un, nibi ti wọn ti pada lọọ fọwọ ofin mu un laipẹ yii. Wọn ni o ti pẹ tawọn ọlọpaa Amẹrika ti n wa afurasi ọdaran naa. Ẹrọ komputa ni wọn lo lo lati lu awọn ọmọ orileede naa ni jibiti owo nla.
Wọn ni laipẹ yii lawọn maa foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ.