Plasma meji ni Tọpẹ ji gbe tọwọ ajọ NSCDC fi tẹ ẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Ọlaleke Tọpe, to jẹ baba ọlọmọ meji, fẹsun pe o ji tẹlifisan Plasma meji gbe ni agbegbe Maraba, Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Agbẹnusọ ajọ naa, Babawale Zaid Afolabi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Hashim Bala Ibrahim, ẹni ọdun mejidinlogoji, to n gbe ni No 16, Adamu Abubakar Road GRA, wa si ọfiisi ajọ ọhun to sọ pe awọn adigunjale ti ji ẹrọ tẹlifisan Plasma meji to jẹ Samsung gbe lọ ninu ile ọhun.

Afọlabi ni lakooko ti Ibrahim gbera nile pẹlu ero lati mu ẹsun lọ si ọfiisi ajọ NSCDC yii pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lo ri ọkọ kan to rọra n lọ diẹdiẹ ni opopona ile rẹ, to si fura si ọkọ naa pe ọkọ ajeji ni. Lo ba tẹle ọkọ ọhun, o si gbiyanju lati da a duro, ṣugbọn dẹrẹba to n wa ọkọ naa tẹna mọ mọto rẹ. ti Ibrahim naa si tẹle e. Agbegbe Maraba lọwọ ti ba afurasi ọhun lasiko to bọọlẹ ninu ọkọ rẹ, to si fere ge e. Pẹlu iranlọwọ ajọ NSCDC, ọwọ pada tẹ ẹ. Wọn wọ mọto rẹ lọ si ọfiisi ajọ naa. Tọpẹ si jẹwọ pe loootọ ni oun pẹlu ẹni keji oun, Majid, lawọn jọ ṣiṣẹ buruku naa, ati pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ, awọn ti n ṣiṣẹ ile fifọ ọjọ ti pẹ. Agbẹnusọ ajọ naa tẹsiwaju pe nigba ti awọn lọọ tu ile ati ṣọọbu afurasi ọhun, Plasma marun-un to to miliọnu naira atawọn eroja miiran ni awọn ba nibẹ.

 

Ọga agba ajọ ọhun nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, ti waa sọ pe ki wọn gbe igbesẹ to ba yẹ, ki wọn gbe afurasi ọhun lọ si ile-ẹjọ.

Leave a Reply