Posita Ṣẹgun Oni gba igboro kan l’Ekiti, wọn lo tun fẹẹ ṣe gomina lẹẹkan si i

Kazeem Aderounmu

Kaakiri awọn ilu kan nipinlẹ Ekiti lawọn eeyan ti n ri posita Enjinnia Ṣẹgun Oni bayii, bo tilẹ jẹ pe eto ipolongo ibo gomina ko ti i bẹrẹ ni ipinlẹ naa.

Ni awọn ibi kan niluu Ado Ekiti bii Ajilosun, Baṣiri, Ijigbo, ojuna Ilawẹ, Okeyinmi, atawọn ilu nla nla bii Ikẹrẹ-Ekiti, Ifaki, atawọn ibomi-in nipinlẹ naa ni wọn ti n ri aworan ọkunrin yii pẹlu asia ẹgbẹ oṣelu PDP to n tọka si i pe o n bọ waa ṣe gomina ipinlẹ naa lẹẹkan si i.

Ṣe ṣaaju asiko yii ni awuyewuye ti n lọ nigboro wi pe ọkunrin naa ṣi tun fẹẹ pada waa ṣe gomina l’Ekiti, ni bayii ti awọn eeyan si ti ri i ninu agbada nla pẹlu fila bii ti Awolowo lori, ti asia ẹgbẹ oṣelu PDP naa tun wa loke tente posita ọhun, lo mu awọn eeyan maa sọ pe ọrọ naa ki i ṣe awuyewuye mọ, ootọ pọnbele ni.

Ohun ti wọn si kọ sinu posita ọhun ni; “Ṣẹgun Oni, fun ipo Gomina, fun ilọsiwaju ọjọ ọla.”

Ẹgbẹ kan to n jẹ Ekiti PDP Progressives ni wọn lo tẹ posita ọhun sita, awọn naa si ni wọn sọ pe wọn n polongo ibo fun ọkunrin oloṣẹlu naa bayii l’Ekiti.

Laarin ọdun 2007 si ọdun 2010, lọkunrin yii fi dari ipinlẹ Ekiti gẹgẹ bii gomina nigba kan, ki igbimọ to n gbọ ẹjọ madaru to waye ninu eto idibo l’Ekiti, eyi ti Dokita Kayọde Fayẹmi pe, ti Adajọ Ayọ Isa Salami si jẹ alaga igbimọ kotẹmilọrun ọhun fi yọ Ṣẹgun Oni danu. Bi Kayọde Fayẹmi, ọmọ ẹgbẹ oṣelu Action Congress ṣe di gomina niyẹn.

Ninu irin-ajo oṣelu ẹ naa ni Ṣẹgun Oni ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC  lọdun 2014 lati kin Fayẹmi lẹyin, bẹẹ oun naa ni igbakeji alaga gbogbogboo ẹgbẹ APC lapa Guusu orilẹ-ede yii lasiko naa.

Ọdun 2020, to kọja yii lo pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹsun to si fi kan Fayẹmi ti i ṣe gomina ipinlẹ ọhun bayii ni pe bii agbelẹhee loun ri ninu ẹgbẹ APC.

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin oloṣelu yii paapaa ko ti i fẹnu ara ẹ sọ pe oun fẹẹ ṣe gomina lẹẹkan si i, sibẹ ̀ohun tawọn eeyan n sọ bayii ni pe pẹlu posita yii, o jọ pe ọkunrin naa n ba nnkan bọ lori idije-dupo gomina Ekiti lọdun 2022.

 

 

Leave a Reply