Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Arakunrin kan to n ṣowo POS, Aafaa Rafiu Akuji, to n gbe ni agboole Akuji, Abáyàwó, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu olu ipinlẹ Kwara, lo ti n rojọ lagọọ ọlọpaa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe owo nla kan, ẹgbẹrun lọna ọgọsan miliọnu Naira (180m), ti ki i ṣe tiẹ ṣeeṣi wọ asunwọn ikowosi rẹ, ti ko si mọ ibi towo naa ti wa. Ṣugbọn dipo ki Rafiu lọọ ṣalaye ọrọ naa fun wọn ni banki, niṣe lo sọ ara rẹ di baba Keresi, lo ba n na owo yafun-yafun.
ALAROYE gbọ pe miliọnu -miliọnu lo n wọle si akanti Aafaa Rafiu, fun bii ọjọ mẹrin gbako, ti gbogbo apapọ owo to wọle ohun si jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọsan miliọnu Naira (180m), ti ko si mọ ẹni to n fi owo naa sọwọ si i, oun paapaa ko si bikita lati ṣewadii ọna towo naa n gba wọ akanti rẹ. N loun ba yaa n nawo lọ ni tirẹ bii ẹlẹda. Bo ti n ra ile, lo n ra ọkọ, bakan naa lo n ra apo irẹsi fun awọn araadugbo, wọn lo tun ran awọn eeyan kan lọ si Umurah, ni lorile-ede Saudi Arabia, lati lọọ gbadura.
Olugbe agbegbe naa to ba ALAROYE sọrọ, to ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri sọ pe lojiji ni Aafaa Rafiu sọ ara rẹ di ẹlẹyinju aanu, to n nawo bii ẹlẹda, ṣugbọn nigba ti awọn fimu finlẹ daadaa ni asiri tu pe owo olowo kan ni Rafiu n na.
‘‘O ran awọn kan lọ si Umurah, ni orile-ede Saudi Arabia, bakan naa lo gbe owo fun awọn eeyan kan laduugbo ki wọn ra apo irẹsi, ki wọn si maa pin-in kiri. Iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo olugbe agbegbe naa bi Rafiu ṣe di olowo lojiji, ṣugbọn lojiji ni ajọ EFCC de pẹlu manija banki kan, ti wọn si gbe Rafiu lọ, ohun ta a maa ri lẹyin eyi ni pe wọn fa a le ọlọpaa lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, SP, Ajayi Ọkasanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ṣalaye pe ẹka to n ṣewadii nipa iwa ọdaran lati Alagbọn-Close, Ikoyi, nipinlẹ Eko, ti waa mu afurasi naa lọ, o ni eyi ni ko jẹ ki ọlọpaa ipinlẹ Kwara lọwọ ninu iṣẹlẹ naa mọ.