Rasaki pa ọmọ mi nitori ọrọ ilẹ ni mo ṣe ran agbanipa si i-Idowu

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Laipẹ yii ni ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ba ọkunrin kan, Idowu Ṣorunkẹ, ẹni to ran  Daniel Ikwe ati Micheal Tedungbe, pe ki wọn ba oun pa ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Rasak Ṣotunde, ti wọn jọ n ja nitori ilẹ kan to wa labule Sọlọmọ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun.

Ọjọ Keresimesi ọdun to ṣẹṣẹ pari yii ni awọn oniṣẹ iku meji ti Idowu ran si Rasak jẹ ẹ, ti wọn lagi mọ ọn lori titi to fi ku. Nigba to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020, awọn ọlọpaa fi oju Idowu atawọn to ran niṣẹ iku naa han ni olu ileeṣẹ wọn l’Eleweeran, nibẹ ni ALAROYE ti fọrọ wa wọn lẹnu wo, eyi lohun ọkunrin naa atawọn to ran niṣe iku sọ.

IDOWU:Rasaki Ṣotunde lo fẹẹ gba ilẹ baba mi lọwọ mi, o fẹẹ da a pọ mọ tiẹ. Nigba ti ọrọ ija ilẹ yẹn kọkọ ṣẹlẹ. Mo kẹjọ lọ sọdọ kabiyesi l’Aṣipa, wọn ni ko ma gbin nnkan sori ilẹ yẹn mọ, ṣugbọn ko gbọ, niṣe lo tun lọọ gbin ọgẹdẹ sibẹ, bi mo ṣe hu ọgẹdẹ yẹn danu niyẹn.

Bi mo ṣe waa hu u danu ni Rasaki waa ba mi pe mo maa ri nnkan toju mi maa ri nitori ọgẹde yẹn.

Ọmọ mi lọọ tọ sori ilẹ yẹn lọjọ keji, ọjọ karun-un ẹ ni ikun ọmọ yẹn bẹrẹ si i wu, mo gbe e kiri titi, afigba tọmọ yẹn ku. Ọmọ to ti dagba, to ti fẹẹ ṣe Wayẹẹki, ọmọbinrin, bo ṣe ku niyẹn. Emi naa tun kọja lori ile yẹn, egbo adaajinna tun mu mi, o ṣẹṣe san ni. Bẹẹ naa lọmọ mi ti ko ti i ju ọmọ ọdun mẹta lọ naa tun bẹre si i ṣaisan, niṣe ni inu iyẹn naa tun bẹrẹ si i wu, mo nawo gan-an ko too gbadun.

Ohun to jẹ ki n ro o pe o yẹ kemi maa tete pa Rasaki niyẹn, nitori oun lo pa mi lọmọ, to tun jẹ ki egbo mu mi. Mi o loogun ti mo le fi pa a ni mo ṣe ran awọn bọisi si i pe ki wọn ba mi pa a, wọn dẹ lagi mọ ọn lori lọjọ ọdun Keresi, bo ṣe ku niyẹn’’

Daniel Ikwe gan-an lẹni to la igi mọ Rasaki lori to fi ku, oun naa ṣalaye pe idaji milọnu ti Idowu loun maa foun boun ba ri iṣẹ naa ṣe lo ran mọ oun loju toun fi gba lati ba a pa a.

O ni ọmọ Igede loun, ni Benue. O ni oun kabaamọ pe oun ṣiṣẹ ibi naa, ṣugbọn ko sohun toun le ṣe mọ bayii. Oun kan fẹ ki wọn ba oun wa foonu koun le pe awọn ẹbi oun pe titan ti de ba aye oun nipinlẹ Ogun o, nitori ẹmi eeyan to ti ọwo oun bọ.

Bakan naa ni Micheal Tedungbe toun ko ju ọmọ ogun ọdun lọ naa sọrọ, o ni  oun loun n ba Daniel ṣọna nigba ti oloogbe n bọ, bo ti kọja loun sọ fun un, o si ni koun gbe igi tawọn fẹẹ la mọ ọn lori wa, koun sun mẹyin.

O ni bi Daniel ṣe bẹrẹ si i lagi naa mọ oloogbe lori niyẹn tiyẹn fi ṣubu lulẹ, nigba naa lo si fa oun lọwọ, to ni kawọn  maa sa lọ.

Awọn mẹtẹẹta ni yoo jẹjọ ipaniyan labẹ ofin ilẹ yii, wọn ko ni pẹẹ ko wọn lọ si kootu gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ.

Leave a Reply