Rasaq ja ero to gbe lole, o tun fiba ba a lo pọ n’Ifọ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Afaimọ ni gende ẹni ọdun mejilelogun to n wa Marwa, Rasaq Taoheed, ko ni i fẹwọn ọlọjọ gbọọrọ jura lori ẹsun ti wọn fi kan an pe ṣe lo yọ ibọn si ero to gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Lẹyin to ja a lole owo tan lo tun fipa ba a laṣepọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to sọ iṣẹlẹ naa di mimọ f’ALAROYE sọ pe ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu Kẹfa yii, niṣẹlẹ yii waye niluu Ifọ, nipinlẹ Ogun.
O ni nnkan bii aago mẹrin idaji kọja iṣẹju diẹ ọjọ naa ni wọn tẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ifọ laago, ti wọn si fi iṣẹlẹ naa to wọn leti. Loju-ẹsẹ ni DPO Ifọ ti ko awọn ọmọọṣẹ rẹ sodi, wọn si sare de ibi tiṣẹlẹ naa ti waye.
Alaye ti obinrin tọrọ naa ṣẹlẹ si ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun ṣe fawọn ọlọpaa to n ṣewadii ni pe oun wọ kẹkẹ Marwa afurasi ọdaran yii ni ibudokọ Pakoto, nitosi Ifọ, oun ni ko gbe oun lọ si Iyana Coker, lọna marosẹ Sango si Abẹokuta, niluu Ifọ. Ṣugbọn bo ṣe n lọ, biri ni onikẹkẹ yii ṣadeede ya kuro lori titi marosẹ, lo ba fa ibọn ilewọ pompo kan yọ si oun, o loun aa yinbọn mọ oun toun ba fi le pariwo, oun nikan loun si wa ninu kẹkẹ rẹ.
Bo ṣe di pe Rasaq gbe obinrin ọhun lọ sileewe pamari Oloṣe, ni adugbo to wọnu kan, niluu Ifọ niyẹn, o ni ko bọ aṣọ rẹ, o si fipa ba a laṣepọ.
Obinrin naa ni bo ṣe n gbo oun mọlẹ lo fọwọ kan mu ibọn dani, igba to si huwa palapala ọhun tan lo tun gba owo ọja to wa lọwọ rẹ, to tun fibọn sin in pada sinu kẹkẹ Marwa rẹ.
Bo ṣe di pe afurasi yii tun dori kẹkẹ rẹ kọ ọna mi-in niyẹn, ṣugbọn nigba ti wọn fi maa gba adugbo kan ti wọn n pe ni Oritameje kọja, awọn eeyan ti wa nibẹ, wọn pọ diẹ, lobinrin yii ba figbe bọnu lojiji pe ki wọn gba oun o.
Kia lawọn eeyan naa ti le kẹkẹ naa mu, wọn da a duro, bi Rasaq ṣe fẹẹ bẹ lugbo ni wọn gan an lapa, wọn gba ibọn ilewọ rẹ, wọn ke sawọn ọlọpaa.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti gbọ nipa ọrọ yii, wọn si ti taari afurasi naa ati kẹkẹ Marwa rẹ, pẹlu ibọn ilewọ to fi n ṣọṣẹ, si awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweeran, fun iwadii to lọọrin.
Ibẹ ni wọn ni wọn ni yoo gba dele-ẹjọ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply