Raymond ati Ekene gba mọto onimọto l’Ekoo, Ogun lọwọ ti ba wọn 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ọjọ akọkọ ninu oṣu kẹfa yii ko so eso rere fawọn ọkunrin meji yii, Raymond Chukwudi ati Ekene Okoro. Aarọ kutu ọjọ naa ni wọn bọ sowọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun pẹlu mọto onimọto ti wọn gba n’Ibeju -Lekki, l’Ekoo.

Ajebandele, aala kan laarin ipinlẹ Ogun ati Ondo lawọn ọlọpaa ti mu awọn mejeeji laaarọ ọjọ naa nigba ti wọn n gbe mọto ayọkẹlẹ Toyota Fortuner ti nọmba ẹ jẹ AGL 834 G U, sa lọ.

Awọn mẹta ni wọn wa ninu mọto naa, bi wọn ṣe n wo tifura-tifura nigba tawọn ọlọpaa da wọn duro, ti wọn ko si le dahun ibeere ti wọn n beere lọwọ wọn lo jẹ kawọn ọlọpaa pe nọmba ẹni to ni mọto ọhun gan-an, eyi ti wọn ri lara iwe ọkọ tawọn eeyan naa ko silẹ.

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni ọkan ninu awọn mẹta to wa ninu mọto ọhun sare bọ sílẹ̀, bo ṣe sa lọ niyẹn. Awọn ọlọpaa si mu awọn meji yooku ti i ṣe Raymond ati Ekene.

Ẹni to ni mọto tawọn ọlọpaa pe sọ fun wọn pe awọn ole naa wọle oun lopopona Iriferiogoma, Lakowe, Phase 2, n’Ibẹju Lekki, l’Ekoo, nibi ti wọn ti gbe mọto oun lọ.

CP Edward Awolọwọ Ajogun ti ni ki wọn ko wọn lọ sẹka itọpinpin, ki wọn si wa eyi to sa lọ naa ri.

Eko ti wọn ti daran ni wọn yoo da wọn pada si to ba ya, ibẹ ni wọn yoo ti towe igbẹjọ wọn bi Ajogun ṣe sọ.

Leave a Reply