Ridwan ha sọwọ ọlọpaa, ọjọ ọdun Ileya lo figi paayan ni Ṣagamu

Adefunkẹ Adebiyi, Abeọkuta

Lọjọ ọdun Ileya to kọja yii ti i ṣe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2020, ni ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn(29) ti ẹ n wo yii, Ridwan Ọtẹmọlu, fi mọto rẹ gba obinrin kan latẹyin, eyi dija laarin oun pẹlu ẹni to jokoo lẹgbẹẹ obinrin ọhun, ni Ridwan ba gbe igi nilẹ, lo ba la a mọ ẹni naa lori, ọjọ kẹrin niyẹn ku sọsibitu, ni wahala ba de.

Ridwan funra ẹ ṣalaye, o ni mọto awọn obi oun to jẹ Lexus loun n wa lọjọ naa lagbegbe GRA, ni Ṣagamu, boun ṣe ṣeeṣi fi mọto naa gba obinrin kan niyẹn, lobinrin naa ba ni koun sọkalẹ waa bẹbẹ.

O loun fẹẹ sọkalẹ ni ọkunrin kan to jokoo lẹgbẹẹ obinrin naa ba bẹrẹ si i ba oun ja, to sọ ohun ti ko kan an di tiẹ, bo ṣe mu ọbẹ niyẹn to fi gun oun nibi eti ati ọwọ, binu ṣe bi oun naa niyẹn toun pada sinu mọto oun, loun ba mu igi kan to wa nibẹ, oun la a mọ ọn lori lẹẹmeji, bo ṣe ṣubu lulẹ ti ko le dide mọ niyẹn.

Wọn gbe ọkunrin naa lọ sọsibitu bo ṣe wi, wọn si tọju ẹ fọjọ mẹrin gbako ṣugbọn iku lo pada ja si, niṣe lọkunrin naa  ku lọjọ kẹrin, latigba naa loun ti wọn wahala.

Ileewe Gateway Polytechnic to wa ni Ṣapade ni Ridwan loun ti kawe, o ni ipele akọkọ(ND) loun pari nibẹ, oun fẹẹ lọọ ṣe HND ni wahala de yii.

Kootu naa ni wọn ni oun naa yoo balẹ si laipẹ, nibi ti yoo ti jẹjọ ipaniyan.

Leave a Reply