Rotimi Akeredolu fa ibinu yọ nigba to foju kan Agboọla, igbakeji ẹ telẹ

Oluṣẹye Iyiade, Akure

Nibi ipade alaafia kan ni wọn pe wọn si l’Ondo, bi eto idibo sipo gomina yoo ṣe waye lopin ọsẹ yii, ti yoo si lọ nirọwọ rọse ni wọn fẹẹ jiroro le lori.

Yatọ si ẹgbẹ oṣelu mẹta to gbajumọ daadaa nipinlẹ naa, awọn mẹrinla mi-in naa wa nibẹ lọjọ yii, gbogbo wọn ni wọn si jọ ṣeleri pe wahala kan bayii ko ni i si ninu ibo to n bọ ọhun ati lẹyin ẹ paapaa.

Bi wọn ṣe pari ti wọn ni ki awọn oludije di mọra wọn  ni Gomina Rotimi Akeredolu to jẹ gomina ipinlẹ naa, to tun fẹẹ pada lẹẹkan si i, fa ibinu yọ, o loun  ko ni i di mọ Agboọla Ajayi, ẹni ti ṣe igbakeji ẹ tẹlẹ. Ati pe oun ko le bọ ọ lọwọ paapaa.

Ki ọro a-n-di-mọra-ẹni too waye ni wọn ti kọkọ kira wọn nibi ipade alaafia ohun, bi Akeredolu, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣe ki Eyitayọ Jẹgẹdẹ, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, bẹẹ ni oun ati Agboọla Ajayi ti Zenith Labour Party naa jọ kira wọn.

Ṣugbọn nigba ti eto pari ti adari eto sọ pe ki Akeredolu ati igbakeji ẹ tẹlẹ bọra wọn lọwọ, tabi ki wọn di mọra wọn, nibẹ yẹn gan-an lọrọ ti fẹẹ daru, ti Akeredolu si juwọ si i, to loun ko ni ọwọ kankan an bọ pẹlu ẹ rara.

Bi iṣẹlẹ yii ti waye lawọn eeyan ti n sọ pe dajudaju, bi Agboọla to lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in ṣe fi ọga ẹ silẹ yẹn ṣi n bi i ninu, wọn ni ọkunrin naa n ri i bii ọdalẹ to fẹẹ ba nnkan jẹ foun ninu idibo naa ni.

Ju gbogbo ẹ lọ, awọn oludije yii ti tọwọ bọwe alaafia, bẹẹ ni ọkọọkan wọn ti ṣeleri pe ko ni i si iwa janduku kan bayii ṣaaju ati nigba ti ibo ba n lọ lọwọ lọjọ Abamẹta, Satide yii.

 

Leave a Reply