Sadik ati Rasak fibọn gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira lọwọ onirẹsi ni Sango

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Sadik Hassan ati Kudus Rasak lẹ n wo yii, awọn mejeeji ti wa ni lọdọ awọn ọlọpaa. Wọn ni wọn yọ ibọn si ọkunrin oniṣowo irẹsi kan, Nonso Nwibo, laduugbo Ipamẹsan, ni Sango, wọn si gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira (120,000) lọwọ rẹ, bẹẹ ni wọn tun mu foonu Tecno to n lo lọ.

Ṣọọbu ti Nonso ti n ta irẹsi lapolapo lawọn ọmọkunrin meji yii ti lọọ yọ ibọn si i laipẹ yii, ti wọn si gba owo ati foonu lọwọ rẹ, niyẹn ba lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Sango.

CSP Godwin Idehai, DPO teṣan naa, atawọn ikọ ẹ tẹle e lọ si agbegbe naa, wọn si ri awọn afurasi mejeeji yii; ṣugbọn bawọn naa ṣe ri ọlọpaa ni wọn ti bẹrẹ si i sa lọ.

Ọkan ninu wọn lọwọ ba, iyẹn Sadiq Hassan, wọn si ba ibọn ilewọ ibilẹ kan lọwọ rẹ. Lẹyin iwadii ti wọn ko yee ṣe, awọn ọlọpaa ri Kudus naa mu, ibi kan to n fara pamọ si l’Owode-Ijakọ ni wọn ti mu un lọjọ Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin yii, wọn si ba ọta ibọn ti wọn ko ti i yin lọwọ rẹ.

Awọn adigunjale mejeeji ti jẹwọ pe awọn lawọn gba owo lọwọ onirẹsi, tawọn si tun gba foonu rẹ pẹlu, gẹgẹ bi DSP Oyeyẹmi Abimbọla ṣe sọ ninu atẹjade to fi kede iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply