Safu halẹ mọ Alaaji, ni dadi wa ba n sare kiri

Baba ti jẹ ẹ tan! Wọn ti gẹẹti baba yin patapata. Alaaji ni, wọn ni kinni ẹ ko tun ṣiṣẹ daadaa mọ. Ohun ti emi o fẹ ninu ọrọ awọn ọkọ wa ti wọn maa n fẹyawo pupọ niyẹn. Ọrọ Ọlọrun ti sọ pe bi ọkunrin ko ba le ṣe deede, ko ma fẹyawo pupọ, ti ko ba ti le pin nnkan dọgba, ko ma ko obinrin jọ. Ṣugbọn Alaaji ki i ṣe bẹẹ, o da bii pe olojukokoro kan lo fẹẹ ya. Bi eeyan ko ba le tẹ awọn obinrin to ba ko jọ lọrun, ki lo n fẹ wọn fun. Ki lo n ko wọn jọ fun. Obinrin kan ṣoṣo to ba wa lọdọ Alaaji lo maa fun lowo ounjẹ, awọn to ku, konikaluku fain wee ẹ ni.

Pe ọkọ mi ti fun mi lowo ounjẹ bayii, ki i ṣe ọrọ ọdun mẹẹẹdogun nilẹ yii. N o kuku fi ba wọn jẹ. Ọlọrun ma jẹ ki n fẹnu mi ba ọkọ mi jẹ, nitori kin ni. Ṣugbọn wọn ki i fun mi lowo ounjẹ. Emi naa ko beere o, nitori Ọlọrun ṣaa ti bu kun mi to bo ṣe yẹ, koda, o kọja ohun ti mo ro, ko si si iye ti mo na lori ọkọ mi ti mo ro lẹẹmeji. Ṣugbọn Alaaji ki i fun Iya Dele naa. Ki i fun un, awọn yẹn ni wọn tun maa n wa gbogbo ọna lati se ounjẹ fun un, ki wọn le roju ire ẹ, ko le waa sun ti wọn. Emi funra mi ni mo mọ bi Iyaale wa agba ṣe n ṣe aye wọn.

Ko si ohun ti Iya mi fẹ ti ko si lọdọ wọn o, ṣugbọn emi ni mo n ra a, Alaaji ki i ba wa da si i, bẹẹ emi kọ ni mo ba a fẹyawo ẹ. Ki i ṣe pe o ni mi lara o, koda, emi ni mo sọ fun Sẹki pe laye ẹ, ko ma ra nnkan kan wa sinu ile yẹn fun iya mi mọ. Nitori gbogbo ohun ti mo ba fẹẹ ra, apo lapo ni mo n ra a fun wọn, tabi ko jẹ paali ni mo maa gbe. Emi naa ni mo si maa n ṣeto awọn ti yoo gbọ ounjẹ wọn, bi ko ba si sọmọ lọdọ mi, funra mi ni n oo se e ki n too jade. Ki i ṣe pe o su mi, ṣugbọn ṣe ẹni to fẹyawo ko mọ pe oun lẹtọọ lati ṣe lori iyawo oun ni.

Eyi ti ko tilẹ waa dara ni ti awọn ohun to n ṣẹlẹ bayii. Ṣe ẹ mọ pe awọn obinrin mi-in ko kọ ki ọkọ ma fun wọn ni owo ounjẹ, tabi pe ko maa ba wọn gbọ bukaata kankan, wọn ko ni i tori iyẹn  binu. Ṣugbọn ohun to maa n bi awọn obinrin mi-in ninu ju ni ki ọkọ ma sun mọ wọn. Awọn kan wa ti wọn o le fi ṣere, wọn fẹran kinni ọhun bii ounjẹ ni. Awọn mi-in si wa to jẹ bo ba jẹ awọn nikan ni wọn wa lọwọ ọkọ wọn, koda ko jẹ oṣu kan lo too raaye sun mọ wọn, wọn o ni i tori ẹ binu. Ohun to le faja ni bo ba jẹ awọn meji ni wọn wa lọwọ ọkọ, ti ọkọ ko waa sun mọ ikan daadaa, tọhun yoo ni o ti lo ara ẹ pa lọdọ ẹni keji oun ni.

Ohun to n ṣẹlẹ si dadi yin bayii niyẹn. Safu fẹjọ ẹ sun mi. Ki i ṣe pe o fẹjọ ẹ sun mi bẹẹ naa, o ni Alaaji n da oun laamu ju bo ti yẹ lọ ni. Mo ni ki lo de? O ni wọn o ni i jẹ ki oun sun bi oun ba wọle, wọn yoo maa fa oun lọmu, wọn yoo maa fi gbogbo ara oun ṣere, oun to si jẹ oun ko fẹ iru nnkan bẹẹ pupọ, nigba ti wọn ba waa daamu oun titi ti kinni naa ba waa wu oun i ṣe, bi oun ba fọwọ kan ‘kinni’ tiwọn, ko ni i ṣiṣẹ mọ, niṣe ni yoo rọ bọjọbọjọ. O ni ni wọn yoo ba ṣaa ni ki oun maa ba awọn fi ṣere, titi ti yoo fi ṣiṣẹ, oun yoo si ṣe bẹẹ, ṣugbọn kinni naa ko ni i dahun.

Kẹ ẹ maa gbọ ọrọ rirun o, Alaaji waa sọ fun un pe ko wi femi ki emi ba a ra oogun ale kan ti mo ra foun lọjọsi. Nigba ti iyẹn sọ fun mi, niṣe ni mo poṣe, oogun ale wo? Emi! Ọlọrun ma jẹ! Mo ni igba kan wa to jẹ loootọ ni kinni ẹ daṣẹ silẹ, ti ko ṣiṣẹ rara, o fẹẹ ku patapata nigba naa ni. Mo ni nitori rẹ ni mo ṣe jade si i, ti awọn eeyan si ba mi ṣe awọn agbo ati oriṣiiriṣii egboogi mi-in, to fi tun bẹrẹ si i ṣiṣẹ pada. Emi naa ran an pada si i, mo ni ko sọ fun un pe ki i ṣe pe kinni ẹ ko ṣiṣẹ o, iṣekuṣe to fi n ṣe lo pọ ju, ko yee sa wale ni gbogbo ọsan mọ!

Ni Safu ba pariwo, ‘Iya mi, ki lẹ n wi yii!’ Mo ni ti mo n wi bii ti bawo, ti oun ba ti sọ fun ọkọ ẹ, yoo ti ye e. Ni Safu ba n bẹ mi, ki n sọ foun, lo ba n fọwọ gbe mi nigbọn bi Sẹki ti i maa ṣe yẹn. Niṣe ni mo n rẹrin-in nigba ti mo ri i bẹẹ, nitori Sẹki nikan lo maa n ṣe bẹẹ fun mi. Ni mo ba sọ fun un. Iroyin ti Iya mi fun mi ni pe ni gbogbo ọsan lo ku ti Alaaji n sa wale bayii, to ba ti jade ṣukọṣukọ, yoo sa pada wale. Ẹni to ba si kọkọ nawọ gan ninu Iya Dele ati Aunti Sikira ni yoo ba lọ. Ṣugbọn ekeji yoo tun pada waa duro de e, bo ba ti n jade niyẹn naa yoo mu un.

Safu ni ‘Haaa!, Baba yii si fẹẹ para ẹ!’ Mo ni ohun to n ṣe ti kinni ẹ ko fi n ṣiṣẹ to ba waa ba a lalẹ niyẹn, awọn iyaale ẹ ti lo o pa lọsan-an ni. Safu ba dide fuu, o ni ki emi maa wo o, oun yoo ṣe ṣeege fun gbogbo wọn. Mo ni, haba, ṣebi iwọ naa ni o o laiki ẹ! Oyinbo to o ṣaa sọ fun mi nijọ yẹn niyẹn!’ Safu dahun pe loootọ loun o laiki ẹ, ṣugbọn oun ko fẹ iwa irẹjẹ ti awọn agbalagba mejeeji n hu soun, wọn ko tilẹ ro toun mọ tiwọn. Baba funra ẹ to si ni oun fẹran oun, oun ko mọ pe baba ti ko mọ ọn kọ ni! Bi wọn ti n gbe e waa ba a lo n ko o jẹ!

Emi o mọ ohun  ti Safu ba Alaaji sọ o, n ko si mọ ohun to ṣe fun un. Mo ṣaa ri i pe ni bii ọwọ iyalẹta, lasiko ti Alaaji maa n lọọ ba awọn Aunti Sikira nile, ọdọ wa lo wa, lo ba jokoo sinu ọọfiisi, lo n ṣere, bẹẹ ni Safu n tọju ẹ, to n lọ, to n bọ. Nigba ti mo si ri i pe ọrọ lọfulọfu wọn fẹẹ le ju, ko ma di pe mo n di wọn lọwọ, mo yaa jade ni temi. Ṣugbọn Alaaji tun wa lọjọ  keji, o tun wa lọjọ kẹta. Mo fẹẹ beere pe ki lọmọ Safu yii lo fun baba yii, ti baba waa fẹẹ di gbẹwudani yii, ṣugbọn n ko sọrọ, ko ma di pe agbaaya loluwa rẹ ni. Afigba toun funra ẹ waa ba mi.

Oun lo waa sọ fun mi  pe ‘kinni’ Alaaji ti ṣiṣẹ o, pe baba n faya lọ bayii ni. Ni mo ba beere pe oogun wo lo lo ti Alaaji fi n waa jokoo ti i ni ṣọọbu. O ni oun sọ fun un pe to ba jẹ ko raaye toun, ki oun wa awọn ọmọ kekere ti wọn maa n waa yọ oun lẹnu bi emi ko ba ti si ni ṣọọbu, ki wọn maa ba oun ṣere, ki oun Alaaji naa si feesi awọn iyawo ẹ to n waa ba nile ni gbogbo ọsan. O ni bi Alaaji ṣe bẹrẹ si i bẹ oun pe ki oun ma ṣe bẹẹ niyẹn, lo ba bura pe oun ko ni i lọ sile lọsan-an mọ, lati fi han an pe oun ko lọ sile loootọ lo ṣe n wa si ṣọọbu yẹn. Iranu!

Ṣugbọn ọrọ ti dija nile ṣaa o, Safu ni bi oun ba ki Aunti Sikira bayii, imu lo ku to fi n da oun loun o.  Mo ni ki loun ro tẹlẹ, ṣe ko mọ pe bi oun ba ti ja Alaaji gba, apapọ ija awọn ẹlẹyẹ loun n wa yẹn ni.

Leave a Reply