Safu loun o fẹ mọto, ọtọ lohun ti ọmọ mi fẹ

Iya Tọmiwa naa waa ki mi o. O kuku wa. Tiẹ lo si ya mi lẹnu ju ninu ọrọ yii. O waa ki mi, lo ni oun waa bẹ mi, ki n ma binu gbogbo ohun ti oun ti ṣe fun mi sẹyin, o ni Aunti Sikira lo tubọ mu ọrọ naa gbona. Mo ni mi o ba a ja, pe oun lo n ba mi ja, mo ni kinni mo fẹẹ ba a ja fun nigba to jẹ ọrẹ ni wa.  Niṣe ni mo rẹrin-in sinu bi mo ṣe n sọ bẹẹ, ẹni to jẹ Ọlọrun lo fi mi kapa ẹ, bi ko jẹ Ọlọrun ni, ohun ti wọn fẹ ko ṣẹlẹ si mi ko daa. Nitori ẹ lo ṣe jẹ gbogbo bo ṣe n wi to, emi o sọrọ ẹ laidaa, koda n ko mẹnuba a rara, iyẹn Aunti Sikira.

Ọlọrun ṣe e, ẹnu ẹ lo kuku fi sọ fun mi pe Sikira lo da gbogbo ẹ silẹ, oun lo waa n gbe ọrọ mi ba oun, to maa sọ ohun ti mo sọ ni aburu foun, ti oun fi n tori ẹ binu. N ko sọ pe bẹẹ ni, n ko sọ pe bẹẹ kọ. Nigba ti mo kuku mọ pe n o sọ ọrọ ẹ laidaa ri, n o sọrọ ẹ lẹyin ri, abọrọ maa ba a jiyan labọrọ maa wahala ara ẹni, mo kan n ni o ṣeun naa ni. Ẹni ti mo mọ, to jẹ bi mo ba sọrọ kan bayii, ohun ti yoo gbe lọ sọdọ ọrẹ ẹ niyẹn, ti yoo ni Iya Biọla sọ kinni kan, ti yoo fi kun eyi ti mo ba sọ, eyi ti mo ba si sọ to jẹ daadaa, ti yoo yọ iyẹn danu. Mo yaa sinmi ẹnu mi.

O kọkọ dupẹ ti owo ati irin mi lọsibitu nigba ti oun fi wa nibẹ, o ni niṣe lawọn ọlọsibitu n beere mi, pe ọrẹ oun yẹn da. Mo ni a ki i dupẹ ara ẹni, pe ohun to dun ninu mi ju naa ni pe o ti gbadun. O si ti gbadun loootọ, ti a ba yọwọ ti pe ẹsẹ yẹn ko tolẹ daadaa mọ, bo si ti ṣe n rin lọ, orin Wasiu Ayinde kan lo n wa si mi lọkan, orin to fi kọ pe ‘Ọta mi o ni i ya fọkọ, akoyọyọ ni yoo kan an lẹsẹ, to ba kan an lẹsẹ tan, aa waa maa rin bayii, tamurege, rin bayii, tamurege!’ Bi Iya Tọmiwa ti ṣe n rin bayii niyẹn. Ka ṣa maa ṣe rere, nitori iwa onikaluku ni yoo da a lẹjọ.

Ọdaran kan si ni Alaaji ni tiẹ, yatọ si inawo ti mo ṣe nijọsi, niṣe loun tun ko awọn ọrẹ ẹ wale, awọn ọrẹ ẹ ninu ẹgbẹ ẹlẹran, to ni afi ki wọn waa ba oun dupẹ, iyawo oun di onile nla l’Oṣodi. Iru ewo niyi Ọlọrun, ile ti a ko ti i kọ. Abi bawo ni baba yii ṣe n ṣe bayii. Emi o wi kinni kan o, mo ṣe wọn lalejo gidi naa ni, nitori oun funra ẹ, iyẹn ọkọ mi, lo ti kọkọ mu ogunfe wale, to ni ki wọn pa a foun, saaraa ti oun fẹẹ ṣe fun iyawo oun niyẹn, oun ko fẹ ki ojukoju wo o, tabi ki awọn abatẹnijẹ kan ba tiẹ jẹ. Inu mi dun si iyẹn, mo si dupẹ titi lọwọ ẹ. Afi ti awọn ọrẹ to ko wa yii.

Onifaaji lawọn yẹn ni. Awọn kan wa ninu wọn to jẹ wọn le da mu katini ọti Guda kan tan, wọn yoo mu un tan, wọn yoo si dide bii ẹni pe ko si nnkan kan to ṣẹlẹ ni. Titi di aago mẹsan-an aabọ, mẹsan-an aabọ ki tiẹ ni, titi di aago mẹwaa kọja, awọn baba yii wa nibẹ. Nigba ti ariwo wọn fẹẹ maa di emi leti ni mo wọle, mo kuku ti ko ọti ti wọn fẹẹ mu fun wọn. Safu paapaa loun ko le ṣe aisun, oun n reti awọn kọsitọma kan ni ṣọọbu, aago meje loun ni ki awọn pade nitori Eko ni wọn n lọ lẹyin ti wọn ba ra ọja wọn tan lọwọ oun, oun ko si le miisi wọn nitori ọti.

Niṣe lọmọ yẹn ma lọọ sun o, ohun to fi aaye gba Aunti Sikira ati Iya Dele niyẹn. Wọn ni wọn jọ n ge bia ni. Iya mi lo royin fun mi, wọn ni awọn ko sun, awọn n woran wọn lati inu yara lọọọkan. Wọn ni ọti paapaa ti wọ Alaaji lara, niṣe ni Aunti Sikira si wọ inu yara ẹ lọ, lo ba pariwo lati ọhun pe Alaaji, Alaaji, ẹ waa ba mi ko kinni yii fawọn alejo o. Ni Alaaji ba dide, nigba to n dide, ara fu Iya Dele, oun naa fẹẹ dide, ṣugbọn ninu awọn ọrẹ Alaaji fi ọrọ da a duro, bi Alaaji ṣe kọja si ọdọ Aunti yẹn niyẹn. Ṣe ẹ mọ pe ko jẹ ko jade mọ. Sitai ti Safu lo lọjọsi loun naa lo yẹn.

Safu ti ko tiẹ raaye, ọmọ ọlọmọ, o ti yaa lọ si ṣọọbu nijọ keji, nigba ti a de ọhun ni mo n fi i ṣe yẹyẹ pe ko duro pari ariya ni wọn ṣe gbe ọkọ ẹ lọ. O ni ewo lo kan oun, oun ko raaye iru faaji bẹẹ lọjọ Sannde, nigba ti oun mọ pe oun n lọ sibi iṣẹ lọjọ Mọnde, ṣe koun de ṣọọbu oun koun maa sun ni. Ọja to si ta laaarọ kutu ọjọ yẹn, laaarọ kutu ọjọ Mọnde, bi a ko ta ọja mi-in titi kanlẹ ọsẹ yẹn, o ti gbe e. Nitori ẹ lemi naa si ṣe pe e jokoo nigba ti a dele lalẹ, ti mo ni ewo gan-an lo fẹ ninu ẹ. Mo ni mo fẹẹ ko ra mọto, ko maa fi ṣe fọrifọri kiri, ko gbe e niṣo l’Agege lati lọọ fi han awọn eeyan.

Lọmọ yẹn ba pariwo, ‘Iyaaaa miii! Ẹ ẹ si pa mi danu!’ Mo ni ki lo de. O ni ṣe tawọn ẹgbọn to wa niwaju oun ni ki oun wi ni tabi ti awọn iyaale oun nile ọkọ, tabi ti awọn ọmọ ti oun fi inu oun bi paapaa, o ni bi wọn ba ri iru rẹ, wọn yoo pa oun jẹ ni, bẹẹ ki i ṣe oogun ni wọn yoo fi pa oun, wahala aye ti wọn yoo ko si oun nigba, oun ko ni i le yanju ẹ, bi ọrọ ba si de oju ẹ, ọrọ ọhun yoo su emi gan-an alara. O ni bi mo ba fẹẹ ṣe oore fun oun, ti owo kankan ba kan oun, ilẹ ni ki n ba oun ra. Oun ko si fẹ ko ju laarin emi ati oun ati ọkọ wa nikan lọ.

O ni ilẹ ki i pariwo, bi oun ba kọle oun kan tan, ti Ọlọrun ran oun lọwọ ti oun kọ ikeji si i, nigba naa ni oun yoo sọrọ mọto. Mo ni abi oun naa fẹ ki n gba ṣọọbu tiẹ fun un ni. Lo ba rẹrin-in, o ni ṣe emi ti mo n pariwo ni gbogbo igba pe irawọ toun ba temi mu, temi naa ba toun mu, ohun ti gbogbo nnkan wa fi ri bo ṣe ri niyi, pe ti oun ba lọọ da gba ṣọọbu sibi kan, oun le ma pa kọbọ lati aarọ ṣulẹ nibẹ, pe ibi ti Ọlọrun da oun si ree, ibẹ si ti tẹ oun lọrun, oun mọ pe ko si ohun ti yoo le oun nibẹ, nitori ọdọ iya oun loun wa, iya oun to ti lọ l’Ọlọrun da pada foun lọna nla.

Ni mo ba ni o ṣeun, bo ti wi la oo ṣe, nitori ọgbọn to daa gbaa ni. A lo ni nibo loun n lọ ti oun n ra mọto, ta lo si mọ oun toun fẹẹ lọọ fi mọto ki. Bi emi naa si ṣe n ronu niyẹn. Nitori ẹ ni mo ṣe pe baba kan ti wọn ba wa walẹ si ọna Ibafo nijọsi, nibi ilẹ mi to wa nibẹ, wọn si ti fọkan wa balẹ pe awọn yoo wa ilẹ gidi fun wa. Emi naa ti waa ni ko si iye to le jẹ, n oo ralẹ naa, a o si bẹrẹ si i kọ ọ. Nitori owo to kan Safu ninu gbogbo ọja ti a ta yii, bo ba fẹẹ kọ ile alaja meji nibẹ yoo kọ ọ. Owo ẹ wa lọwọ mi, n ko si ni i fi da a lagara, n ko si ni i jẹ ẹ mọlẹ, lodidi ni n oo ba a tọju ẹ titi ti yoo fi ṣe ohun to fẹẹ ṣe. Ki Ọlọrun ran mi lọwọ.

Leave a Reply