Safu ni Iya Dele at’Anti Sikira fẹẹ gbooru ara ninu ojo ni

Ọjọ keji ni mo too le ṣalaye ohun to ṣẹlẹ nile fun Safu.  Nigba ta a de ṣọọbu ni mo ṣalaye fun un. Mo ti kọkọ ro pe boya ki n ma wi fun un, mo tun tun un ro pe ko daa. Ọlọrọ abi eti didi ni, oun ko mọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ pata, bẹẹ igba ti emi tun dele, iya mi tun tu pẹrẹpẹrẹ awọn ohun to ṣelẹ lẹyin ti mo ti lọ tan fun mi. Wọn ni gbẹgẹdẹ gbina, pe kekere lemi ri ti mo ro pe mo ri nnkan. Wọn rọra n sọrọ fun mi ni o. Ninu yara ni mo ti lọọ ba wọn, wọn ko si fẹ kẹni to ba n kọja lọ nita gbọ. Ni wọn ba n yọ sọ fun mi, wọn ni ki n ṣe bii ẹni pe n o gbọ ni o.

Ṣugbọn mọ gbọdọ sọ fun Safu. O ṣa yẹ ki n ṣalaye fun un idi ti mo fi pẹ ki n too de ṣọọbu, nigba to jẹ emi ni mo ni ko maa niṣo, n ko ni i pẹẹ de. Emi gan-an kọ ni mo tiẹ bẹrẹ ọrọ ọhun, oun lo bẹrẹ ẹ, lẹyin to ti sọ bi wọn ti ṣe gbogbo iṣẹ wọn si lanaa fun mi. Ọmọ alaje lọmọ yẹn sẹ, gbogbo bo ṣe n royin ohun to ṣẹlẹ, mo kan n wo ẹnu ẹ ni. Awọn apo irẹsi kan, ati miliiki alagolo, pẹlu ọṣẹ ta a ti ko silẹ lati ọjọ yii, awọn kan si wa si ṣọọbu, wọn si fẹrẹ ra gbogbo ẹ tan pata. Ẹgbẹrun lọna irinwo, fọọ handirẹẹdi ni Safu pa lọjọ akọkọ to lọ si ṣọọbu.

O ni bi kafinta ṣe ṣe paanu to ṣi danu tan lawọn gba sọọbu, ti oun si ni ki awọn ọmọ bẹrẹ iṣẹ, ki wọn ko gbogbo ọja sita. Nibi ti wọn ti n to ṣọọbu lawọn eeyan naa ti de, ti wọn ni wọn n ra ọja naa lọ silẹ Hausa. O ni Hausa ni wọn, ṣugbọn wọn gbọ Yoruba. Pe bi oun ṣe duro ti wọn niyẹn, ni wọn ba ta apo irẹsi ta a ṣi n wa ẹni si ni ogun ẹgbẹrun fun wọn lẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn, to tun ni inu wọn dun lati ko o. Mo ni ki lo de, iye ta a ra a ma kọ niyẹn, ere yẹn ti pọ ju. O ni ṣe emi o mọ pe ta a ba tun fẹẹ ra bayii, owo ti a maa ra maa pọ ju ti tẹlẹ lọ ni.

Nigba to sọ bẹẹ, niṣe ni mo mi kanlẹ, nitori ootọ lo sọ, Ọlọrun lo mọ iye ti awa naa yoo tun gba a bayii ti wọn ba fẹẹ ko o wa. Mo ni bawo ni wọn ṣe loodu ẹ. O ni awọn jọ loodu ẹ ni, pe Raṣida ati Abbey n wo oun ni nigba ti oun n ba wọn gbe e, abi nigba ti wọn o tete ri awọn mọla to le ba wọn loodu ẹ, to si jẹ awọn mẹta lawọn naa, ti wọn wa n gbe e funra wọn, ṣe koun maa wo wọn ni. O ni inu mọla to lẹru naa dun debii pe ẹgbẹrun marun-un lo foun. Inu emi naa dun si i, mo si mọ pe n oo fun un lowo gidi. O mọ ọrọ aje i ṣe pupọ.

Bi ọrọ ti ri niyẹn, awọn ọmọ ti wọn ti wa lọdọ mi lati ọjọ yii, awọn o le ba wọn fọwọ kun apo irẹsi, ti mo ba wa nibẹ ni, wọn maa ma ṣoju aye, to ba waa ya, wọn aa ni o fẹran ẹni kan ju ẹni kan lọ. Funra wọn naa kuku tiẹ sọ fun mi, Abbey ni emi o duro ki emi waa woran, ki n waa wo Anti Safu ti wọn wa apo irẹsi maya bii ọkunrin, ni Raṣida naa ni, ‘agbara wa lara mọmi yẹn o.’ Inu bi mi nigba ti Safu ni oun fun wọn ni ẹgbẹrun kọọkan, mo ni ki lo fun wọn si, ṣe wọn ba a gbe nibẹ ni, abi iru aye palapala wo niyẹn. Awọn onibajẹ omọ. Iyẹn tun jẹ ki n ranti pe emi naa maa fun un lowo daadaa.

Mo mọ pe igba ti a ba dele ni mo too maa fun un, ko ni i jẹ ṣọọbu, n o ni i jẹ kawọn oniranu ọmọ wọnyẹn mọ ohun to n lọ. Awọn ti ọlẹ ti fọ lori! Ẹgbẹrun marun-un marun-un to le lori apo kọọkan yẹn, ẹgbẹrun meji aabọ ni tiẹ nibẹ, apo mọkanla ti wọn si ra yẹn, owo tiẹ jẹ ẹgbẹrun metadinlọgbọn ataabọ. O digba ti n ba ko o fun un ki n too ṣalaye bo ṣe jẹ fun un, koun naa le mọ pe gbogbo ohun ti ẹda ba ṣe lo lere, ko si le mọ iru iya tuntun to ni, pe n ki i ṣe alajẹpa, tabi ẹni ti owo ka lara ju ẹmi ẹ lọ.

Igba ti a sọ eleyii tan lo ba kunlẹ, lo ni ki n ma binu o, oun fẹẹ beere ọrọ kan lọwọ mi ni. Mo ni ki lo de, o ni ṣe bi Alaaji ti maa n han-an-run rẹpẹtẹ lẹẹkọọkan bi wọn ba sun niyẹn, nitori iṣọwọ-han-an-run wọn lanaa buru pupọ debii pe aya oun n ja, nitori wọn o han-an-run bẹẹ ri lati igba ti oun ti de. O loun fẹẹ sare waa pe mi ko ma jẹ nnkan kan n ṣe wọn ni. Mo ni ko ma da ọkọ ẹ lohun, pe awọn iṣẹ to ṣe lanaa lo fa ihan-an-run. Lo ba sare dide, lo wọ ijokoo mọ mi lẹgbẹẹ. Eke lọmọ Safu yii naa fẹe ya. Ni mo ba ṣalaye oun to n ṣẹlẹ ki emi too kuro nile fun un. Lo ba n rẹrin-in, o ni, ‘Awọn iya fẹẹ gbooru ara ninu ojo niyẹn o!’

N o mọgba temi naa rẹrin-in, mo ṣẹṣẹ waa ṣalaye eyi ti iya mi sọ fun mi pe nigba ti emi jade, ti Alaaji ko tete jade nibi to wa, ni Iya Dele ba bẹrẹ si i gbalẹkun, nigba ti ko ṣiwọ l’Aunti Sikira ba fibinu jade, ni wọn ba n pariwo mọ ara wọn. Nigba ti ọrọ fẹẹ dija ni Alaaji ba sa jade. Njẹ ko sa wọ inu palọ ẹ, bi Iya Dele ṣe gan an lọwọ niyẹn, lo ba n wọ ọ lọ tuurutu sinu yara tiẹ, ni Aunti Sikira ba n fi i rẹrin-in, wọn lo n sọ pe, ‘Ẹ jẹ ma ṣera yin leṣe iya, ajẹku mi lẹ n lọọ jẹ yẹn. Mo yọnda fun yin, ẹ jọ lọọ gbadun ara yin!’ Ni Safu ba ni, ‘Mọmi yẹn o ma daa o, igbadun wo lo wa ninu iyẹn, lẹni to ti lo pa!’

Ni mo ba ni abi oun Safu funra ẹ n wa nnkan lalẹ ana ni. Lo ba rẹrin-in, o ni, ‘Iya mi, mo ti sọ fun yin pe ẹyin lemi jọ. Iṣẹ aje lemi n wa. Emi o kundun kinni ọhun, kọkunrin kan o maa waa gbooyan mọlẹ bii kẹmi o fẹẹ bọ, beeyan ba n ṣe kinni ọhun ju, oluwarẹ yoo kan darugbo ọsan-an-gan ni!’ Mo ni iwọ o si fẹẹ darugbo?’ Lo ba fo dide, o ni, ‘Darugbo kẹ! ṣe iya mi ti mo jọ yii darugbo ni, ẹyin tẹ ẹ ri bii sii-sistin!’ Ni Safu ba foyinbo pari ọrọ o.

Mo ti gbagbe! A tun lọọ wo Iya Tọmiwa o. Wọn ko ti i yọ kinni lẹsẹ ẹ, o wa nibi ti wọn ka a rọ si. Dokita ti mo tiẹ ba sọrọ ko fọkan mi balẹ, o loun o ti i le sọ, ko ma jẹ awọn maa ge ẹsẹ yẹn ni o. Ojoojumọ ni Sẹki n lọ sibẹ,  ṣugbọn ọkọ wọn, Dele, ko jade o. Wọn lo ni yoo maa yọ oun lẹnu bi oun ba jade si i ni, ko ni i jẹ ki oun gbadun ni iṣẹju kan bayii. Abiru awọn ọkunrin wo lo wa lode bayii. Ẹyin naa, ẹ ṣaa maa ba mi gbadura fun Iya Tọmiwa, Ọlọrun ma jẹ ki wọn ge e lẹsẹ o!

Leave a Reply