Ẹ ẹ wa gba mi! Oniranu! Ọmọkunrin kan bayii ma ni o. Awọn ọmọ ti wọn maa n pe ara wọn ni aafaa ti wọn maa n bora yẹn ni, ti wọn maa ni awọn n riran, awọn n ṣe iṣẹ aafaa. Mo ṣaa ri i to ni oun waa beere owo apo irẹsi, to ni awọn ni ṣiṣe kan, awọn fẹẹ ra irẹsi apo mẹẹẹdogun. Emi kọ lo ba o, Safu lo ba nibẹ. Safu, gẹgẹ bii iṣe tiẹ, ṣaajo aje, o tun ra miniraasi fun un, nigba to ni oun n lọ ki oun pada waa ra a. Ko pada wa nijọ yẹn, ọjọ keji lo pada wa, ohun to si sọ fun Safu ni pe awọn ti sun ọjọ inawo siwaju. Lo ba ni Safu loun wa wa.
Bo ṣaa ṣe bẹrẹ si i fi ọrọ dundun tan iyẹn jẹ, to n lanu, to n pa a de niyẹn. Emi wa ninu ṣọọbu lọhun-un, mo n gbọ gbogbo kantakantan to n sọ, ni Safu naa ti n rẹrin-in wẹndẹnwẹndẹn, ni mo ba feti silẹ daadaa. Mo mọ pe Safu ki i ṣe ọmọ bẹẹ, ko si raaye iru ere palapala ti ọmọ aafaa naa n ba a ṣe, nibẹ lara ti fu mi. Ko ma jẹ awọn ọmọ fọọ-wan-nain ti wọn n wi ni, awọn ọmọ onijibiti. Bọkan mi ṣe sọ bẹẹ ni mo sare jade, ohun ti mo si ri fi han mi pe ọkan mi o tan mi jẹ. Safu ti na ọwọ siwaju, aafaa iranu naa fẹẹ bu kinni kan sọwọ ẹ, ni mo ba pariwo!
Safuuu! Lọmọ mi ba tagiri, ‘Iya mi!’ Lo ba sare fa ọwọ ẹ pada sẹyin, lo wa n beere lọwọ aafaa pe ki lo fẹẹ rọ si oun lọwọ, niyẹn ba bẹrẹ si i kololo. Ọlọrun lo mọ ohun to ti lo fun ọmọ ọlọmọ ti iyẹn ko mọ ohun to n ṣe mọ. Nigba to ri mi ti mo jade yẹn, ti Safu ti bẹrẹ si i beere ọrọ lọwọ ẹ, niṣe lo bẹrẹ si i fi ẹyin rin, afi foki to fo jade. Safu pariwo, ‘ooole!’ O fẹẹ sare jade tọ ọ, ni mo ba fa a pada, mo ni ko fi i silẹ ko maa lọ. Ohun to jẹ ki n ṣe bẹẹ ni pe bi n ba jẹ ko pariwo ole le e bẹẹ, tawọn ọmọ Oṣodi ba gba ya a, wọn maa lu u pa ni.
Kinni ki n waa wi ti wọn ba ṣe bẹẹ ti wọn lu u pa, kin ni mo fẹẹ sọ. Ariwo ẹ ko ni tan nilẹ, wọn aa ni ṣọọbu Iya Biọla ni wọn lu u pa si. Tabi ki wọn tiẹ bẹrẹ isọkusọ mi-in pe Iya Biọla fi ṣaajo owo ẹ ni. Wọn le ni ko si bi eeyan ṣe le maa ri ṣe bẹẹ yẹn ti ki i baa ṣe pe o tẹ ẹ nidii, wọn yoo ni mo fi i rubọ ni, wọn o ni i pe e ni onijibiti mọ. Ohun ti mo sare ro paapaapa ti mo fi ni ki Safu ma pariwo ole le e lori niyẹn, mo ni o maa ko onitiẹ niwaju. Igba ti mo si sọ fun Safu naa, ọrọ naa ye e, o ni oun o ro o bẹẹ rara, oun iba laiki ẹ ki wọn lu u pa.
Emi o ni i jẹ ki iyẹn ṣẹlẹ ni sakaani mi, Ọlọrun o ni i jẹ a ṣoriburuku, ẹlẹnu meji lawọn eeyan, ẹnu ni wọn maa fi pe adegun, wọn aa tun ni adeogun, bi wọn ṣe n pariwo Iya Biọla si daadaa yẹn lo daa, Ọlọrun ma jẹ ki wọn ri ohun kan to ku diẹ kaato, wọn o ni wadii ẹ rara, wọn aa yi ilu pada kiakia ni. O tiẹ waa gbebẹ, Safu gan-an to n ṣe eleyii, mo ṣẹṣẹ ba a ra ilẹ to fẹẹ kọ ile si ni Mowe ni o. Ko jinna rara si ilẹ mi to wa nibẹ, awọn baba ijọsi yẹn naa ni wọn ba mi wa ilẹ ọhun, nigba ti mo si beere pe ṣe Safu fẹ Mowe, ẹ ẹ gbọdọ gbọ ohun to fi da mi lohun.
‘’Iyaa mi, koda ko jẹ oko Ibadan, ani ki emi naa tiẹ kọle laye mi! Ṣe emi ro pe mo le kọle ni! A waa wi tan, ẹ ni Mowe, ṣe ilu nla kan wa to tun ju Mowe lọ ni!’’ Ni mo ba yaa sinmi, ti n o wi nnkan kan mọ, ko ma di pe oluwa ẹ ko mọ oore Ọlọrun. Ọjọ yẹn lawọn ti wọn ba mi ra ilẹ ẹ ni ka wa o, ka waa lọọ mọ ibi ti wọn ri i si ni o, ti mo si ti ni ki wọn ba wa ṣe gbogbo ẹ ka le ṣe iwe ẹ lẹẹkan, ọjọ yẹn ni olori-ma-ṣanfaani ọmọ onijibiti kan yoo waa pa ara ẹ si ṣọọbu mi, ki wọn le maa pariwo pe mo paayan, Ọlọrun ma jẹ.
Nigba ti gbogbo ẹ ṣaa lọ silẹ, ti ọkan ti balẹ, ti awọn Abbey ati Raṣida ti de ṣọọbu, a dagbere pe awa n lọ sibi kan. Ba a ṣe lọ si Mọwe niyẹn. Nibẹ la ti ri awọn onilẹ. Ọlọrun funra ẹ lo si ba Safu wa ibẹ yẹn o, Ọlọrun ni. Ohun ti mo n sọ nipa inu ire naa niyẹn, Ọlọrun mọ bo ṣe maa n san awọn eeyan rẹ lẹsan. Ohun ti mo ṣe sọ bẹẹ ni pe ki i ṣe ẹsan ohun ti Safu ṣe lemi san fun un, Ọlọrun lo san an lẹsan ohun to ṣe. Ilẹ ti wọn ni ko waa ra yii, ile ti wa lọtun-un, o ti wa losi, koda ẹni to ra a tẹlẹ ti ṣewe ẹ, wọn ni iyẹn lọọ ra ilẹ mi-in si Lekki lo ṣe fẹẹ ta a.
Igba ti mo si ti ri i ni mo ti ni gbogbo ohun to ba gba ni n oo fun un, mo gbọdọ ra a fun Safu ni. Owo ti wọn fẹẹ ta a ko si to iye ti mo ti ni lọkan tẹlẹ, loju-ẹsẹ nibẹ naa la si sanwo, ti wọn ya fọto, ti wọn ṣe fidio, ti wọn ko iwe fun wa. Awọn gan-an ni wọn n kan wa loju pe ka tete waa bẹrẹ nnkan lori ẹ, ko ma di pe ibẹ yoo wọ awọn eeyan loju, nitori ẹni to ra a tẹlẹ ko ṣe fẹnsi si i. Ohun ti mo si kọkọ ṣe naa niyẹn. Oju ọna ni mo ti pe baba onibulọọku mi to wa ni Ṣogunlẹ, ti mo ni ko pade mi ni ṣọọbu lọwọ ọṣan.
Mo ti yanju iyẹn ki n too kuro ni ṣọọbu, mo si ti fun un ni adirẹsi, mo fun un ni foonu ẹni to maa pe, ọkan ninu awọn ọmọ baba to n ba mi mojuto ilẹ mi nibẹ naa ni, mo ni iyẹn maa fi ilẹ han wọn, pe ki wọn tiẹ kọkọ mọ fẹnsi si i, ki wọn si lọọ ra geeti sibẹ. Nigba ta a maa pada lọ sibẹ ni Satide, wọn ti mọ fẹnsi giga si i, wọn si ti gbe geeti si i, niṣe lawọn baba yẹn lanu silẹ nigba ti wọn tun ri mi, wọn ni olowo ṣehun gbogbo tan ni wa, pe lọjọ wo sijọ wo, gbogbo ibẹ ti yipada kia loootọ.
Ṣugbọn mo mọ pe iyẹn kọ ni mo fẹẹ fi ya wọn lẹnu, eyi ti mo fẹẹ fi ya wọn lẹnu ni ile yẹn funra ẹ. Lagbara Ọlọrun, ka too bẹrẹ ile Oṣodi yẹn, ile Safu maa yanju. Owo mi kuku kọ ni mo fẹẹ fi ṣe e, owo ẹ naa ni, owo ti awọn araata iba gba lọwọ mi bi ki i ba ṣe oun lo mojuto gbogbo irẹsi ta a ta fawọn ara Abuja yẹn ni. Owo temi ti wa lọwọ mi, ki i ṣe owo ti mo le fi kọ ile nla mẹrin tan, owo ti emi naa ko le sọ bi n oo ti na an ni. Ki waa ni n oo tun jẹ owo tiẹ mọlẹ si, Ọlọrun ma jẹ, ile ẹ ni mo kọkọ fẹẹ yanju. Bi a ba ti fi ọgbọn sọ fun Alaaji tan, iṣẹ bẹrẹ niyẹn. Ki Ọlọrun fun mi ṣe, ki oore ma si dibi mọ mi lọwọ o.