Saheed ji mọto ọga ẹ l’Ondo, Ilaro to ti fẹẹ ta a ni wọn ti mu un

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọwọ ikọ fijilante So-Safe ti tẹ ọkunrin kan, Saheed Erinfọlami n’Ilaro, nipinlẹ Ogun. Ọkọ bọọsi to fi n ba ọga rẹ pin burẹdi fawọn onibaara l’Ondo lo gbe sa wa s’Ilaro, nibi to ti n ṣeto ati ta a ni wọn ti mu un.

Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, lọwọ ba Saheed; ẹni ogoji ọdun. Ohun ti ACC Mọruf Yusuf, Alukoro So-Safe, sọ nipa iṣẹlẹ naa ni pe ileeṣẹ burẹdi kan ti wọn n pe ni Igbẹyinaadun, ni Saheed n ba ṣiṣẹ nipinlẹ Ondo.

O ni dẹrẹba ni wọn gba a fun nibẹ, oun lo maa n ba wọn wa bọọsi ti nọmba ẹ jẹ REE 907 XA, to fi n pin burẹdi kiri.

O pin burẹdi tan ni ko pada s’Ondo mọ, ipinlẹ Ogun lo mori le, n’Ilaro, lọdọ ẹgbọn rẹ kan to gbagbọ yoo ba oun ta mọto naa silẹ Olominira Bẹnẹ, nitori ọmọ Bẹnẹ ni Saheed yii naa.

Ṣugbọn nigba ti ọga rẹ ko ti ri i ko pada wale pẹlu mọto niyẹn ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, wọn si ti n wa Saheed Erinfọlami ati bọọsi naa.

Nigba ti olobo waa ta awọn So-Safe nipa ibi ti afurasi naa fi ṣe ibuba n’Ilaro, wọn wa a debẹ, wọn si mu un. Ko ti i ri mọto naa ta si Bẹnẹ, bi wọn ṣe mu un ti wọn so nọmba ara ọkọ naa mọ ọn lọrun niyẹn.

Awọn So-Safe ti fa a fawọn ọlọpaa ẹkun Ilaro fun itẹsiwaju iwadii ati ki wọn le gbe e lọ si kootu.

Leave a Reply