Samalia ja ṣọọṣi lole l’Ojodu, apoti ọọrẹ lo ji gbe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ileejọsin Grace Nations Church, to wa l’Ojodu Abiọdun, nipinlẹ Ogun, ni ọkunrin yii, Mela Samaila, ti n ṣiṣẹ ọlọdẹ tẹlẹ, aṣemaṣe ni wọn lo ṣe nibẹ ti wọn fi le e danu. Afi bo ṣe tun fo fẹnsi wọbẹ l’Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu kin -in-ni, ọdun yii, to ji wọn lapoti ọrẹ gbe lọ pẹlu owo ninu.

Awọn ọlọdẹ to n ṣọ ṣọọṣi naa bayii ni wọn pe teṣan ọlọpaa Ojodu Abiọdun laago mẹ́rin aarọ ọjọ naa, pe ole kan fo iganna wọnu ṣọọṣi yii, o si gbe apoti towo ṣọọṣi naa wa ninu ẹ lọ.

Eyi ni DPO teṣan ohun, Csp Eyitayọ Akinluwade, fi ko awọn eeyan rẹ lọ sibẹ, ti wọn fọ gbogbo agbegbe naa yika, ti ọwọ wọn si pada ba Samaila pẹlu apoti ọrẹ naa lọwọ rẹ.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi sọ pe pẹlu iranlọwọ awọn ọlọdẹ to n ṣọ ṣọọṣi ti wọn tun n pe ni Liberation City yii, ni wọn fi ri Mela mu, ti wọn si gba apoti owo naa lọwọ rẹ.

Ni bayii, CP Edward Ajogun ti ni ki wọn gbe ọkunrin naa lọ si kootu ti iwadii ba tipari lori ẹ.

Leave a Reply