Samson yii ma daju o, o tan onikẹkẹ Marwa mẹta lọ sile ẹ, o pa wọn, o si ji kẹkẹ wọn lọ

Faith Adebọla

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ọdaju adigunjale ati apaayan kan, Samson Eze, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31), latari bo ṣe tan awọn onikẹkẹ Marwa mẹta kan lọ sile rẹ, o kọlu wọn, o si pa wọn, lẹyin to wọ oku wọn ju sinu sọkawee kan lẹyinkule ile ọhun lo gbe kẹkẹ Marwa wọn sa lọ.

Gẹgẹ bi Bartholomew Nnamdi Onyeka to jẹ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Plateau tiṣẹlẹ naa ti waye ṣe sọ lasiko to n ṣafihan afurasi ọdaran naa lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Jos, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, o ni ki i ṣe ẹẹkan naa lafurasi ọdaran yii ṣiṣẹẹbi ọwọ rẹ fawọn oloogbe ọhun, o niṣe lo n fẹtan mu wọn lọkọọkan.

Gẹgẹ bo ṣe wi, agbegbe ile kan to wa lagbegbe Kampala, lọna Rukuba, nipinlẹ Plateau, ni ọkunrin naa n gbe, ọjọ Satide ati Sannde ọsẹ to kọja yii lo ṣiṣẹ buruku ọhun.

Wọn niṣe ni Samson sọ fawọn onikẹkẹ naa pe oun fẹ ki wọn ba oun ko awọn ẹru kan nile oun lọ sibi kan, bawọn yẹn ba si ti tẹle e wọle lati wo ẹru irọ ọhun, niṣe ni yoo fin kẹmika oloro kan si wọn nimu lojiji, lẹyin ti tọhun ba ti ku ni yoo gbe kẹkẹ Marwa rẹ, yoo si gun un lọ sile tuntun kan to ṣẹṣẹ kọ pari lagbegbe Agingin, niluu naa.

A gbọ pe ẹgbọn rẹ kan lo fura si bi afurasi ọdaran naa ṣe di onikẹkẹ Marwa mẹrin lojiji, lo ba ta awọn ọlọpaa lolobo, ti wọn fi dọdẹ rẹ, ti wọn si mu un ṣikun.

Wọn ni Samson ti jẹwọ pe loootọ loun huwa buruku naa, o si mu awọn ọlọpaa lọ sinu sọkawee to wọ oku awọn onikẹkẹ to ja lole si, oku mẹta ni wọn wọ jade, awọn kan lara oku ọhun ti n jẹra, ṣugbọn awọn ọlọpaa wọ wọn jade, wọn si ya fọto ati fidio wọn gẹgẹ bii ẹsibiiti.

Samson jẹwọ sọ fawọn agbofinro pe owo toun maa fi rinrin-ajo lọ siluu oyinbo loun n wa, toun fi huwa ọdaran yii.

Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii bi kọmiṣanna ọlọpaa ṣe wi, o ni Samson yoo foju bale sile-ẹjọ laipẹ, lati fimu kata ofin.

Leave a Reply