Sanni Abacha ti tun fi biliọnu meji ataabọ naira ranṣẹ sawọn ọmọ Naijiria ‘lati ọrun’

Lati ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun 1998, ti Ọgagun Sanni Abacha to ti figba kan jẹ olori orileede yii ti ku, o fẹrẹ ma si ọdun kan, tabi asiko ijọba kan, ti aṣiri awọn owo buruku ti ọkunrin naa ko pamọ sawọn orileede loke okun ko ni i tu, ti awọn orileede naa yoo si da awọn owo ọhun pada fun ijọba Naijiria. Lati aye Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni wọn ti n gbowo Naijiria ti Abacha ji ko pamọ sawọn ilẹ okeere. Bẹẹ ni wọn gba obitibiti owo laye ijọba Goodluck Jonathan. Owo ti wọn si ti tun ri gba lawọn orileede kaakiri latigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti debẹ yii ko mọ niwọn.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a lo tan yii, ni orileede Ireland tun kọwọ bọwe adehun pẹlu ilẹ wa lati tun da miliọnu marun-un ataabọ Yuro pada fun Naijiria. Eyi jẹ owo ilẹ wa ti Abacha ko pamọ sorileede naa. Ba a ba ṣẹ ẹ ni owo ilẹ wa, bii Biliọnu meji ataabọ le diẹ (2, 515, 639, 583.60) ni yoo ku si

Minisita eto idajọ nilẹ Irish to fi eleyii lede, Helen McEnteen, sọ pe igbesẹ lati da owo yii pada fun ilẹ Naijiria waye lẹyin ti ile-ẹjọ ti faṣẹ si i pe ki ijọba ilẹ naa gbẹsẹ le owo ọhun lọdun 2015. Minisita yii sọ pe banki kan to wa ni Dublin ni wọn kowo ọhun pamọ si, ileeṣẹ to si n ri si iwa ibajẹ ati ajẹbanu tiwọn niluu oyinbo to da bii EFCC tiwa nibi lo ṣawari owo naa 2014. Lẹyin igbẹjọ ni ile-ẹjọ wọn lọhun paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹ le owo ọhun.

Laarin ọdun mejidinlogun si asiko ta a wa yii, owo ti awọn ijọba wa ti ri gba pada ninu owo ti Sanni Abacha ji ko nilẹ Naijiria, to ko pamọ silẹ okeere lasiko to fi n ṣejọba ti to biliọnu marun-un dọla o din diẹ ($4.6b) Awọn orileede ti wọn ti gba awọn owo to pọ ju lọ ni Switzerland, Jersy Island, ni UK, orileede Amẹrika ati Liechtenstein.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

One comment

  1. Asiwere n ko ORO Jo ni awon eeyan ti won n SE asiwaju wa.

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: