Sanw-Olu ti dariji Funkẹ Akindele ati ọkọ ẹ, o ti fawe ẹwọn wọn ya

Faith Adebọla

Ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa to gbajumọ daadaa nni, Funkẹ Akindele, tawọn ololufẹ ẹ mọ si Jẹnifa, ati ọkọ rẹ, AbdulRasheed Bello ti gbogbo eeyan mọ si JJC Skillz ko ni i gbagbe ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, bọrọ.

Eyi ko ṣẹyin bi Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣe kede pe ijọba ti dari ẹṣẹ ti wọn jẹbi rẹ lasiko Korona jin wọn, wọn ti dẹni ominira patapata bayii.

Leave a Reply