Sanwo-Olu ṣeleri ẹkọ-ọfẹ fawọn ọmọ ọlọpaa ti wọn pa lasiko iwọde SARS

Aderohunmu Kazeem

Lasiko ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ṣabẹwo sileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lo kede ẹkọ-ọfẹ fawọn ọmọ ọlọpaa ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko rogbodiyan SARS to waye niluu Eko. Bẹẹ lo tun ni o ṣee ṣe ki ijọba ṣeto madamidofo (Insurance) fawọn to ṣi wa lẹnu iṣẹ. O tun fi kun un pe oun yoo tun gbogbo awọn agọ ọlọpaa to jona kọ si ti igbalode.

Olu ileesẹ ọlọpaa to wa ni Ikẹja, ni gomina ti ṣeleri yii lasiko to ṣe abẹwo si wọn pẹlu Igbakeji rẹ, Babafẹmi Hamzat, atawọn ọmọ igbimọ ijọba rẹ kan, ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nibi to ti ṣeleri fun awọn agbofinro naa pe gbogbo ibeere awọn ọdọ lasiko iwọde SARS nijọba oun yoo dahun si.

Lara awọn ileri ti gomina ṣe ni pe ijọba oun yoo mojuto eto isinku gbogbo awọn ọlọpaa to ku lasiko SARS. O lawọn yoo ṣeto owo ‘gba ma binu’ fun gbogbo mọlẹbi awọn agbofinro to ku lasiko rogbodiyan ọhun.

Siwaju si i, Sanwo-Olu ni oun yoo ṣeto ẹkọ-ọfẹ fawọn ọmọ ọlọpaa to ku lasiko wahala SARS yii. O ṣeleri jẹneretọ meji fun olu ileeṣẹ ọlọpaa naa n’Ikẹja.

Gomina ni asiko ti to lati ṣatunṣe si ajọsẹpọ to wa laarin ọlọpaa atawọn araalu.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu atawọn agbagba lẹnu iṣẹ naa lo wa nibẹ.

Leave a Reply