Sanwo-Olu ṣeleri ipese ohun amayedẹrun to pọ si i lọdun 2021

Faith Adebọla, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti sọ pe ipese awọn ohun amayedẹrun lo maa jẹ iṣakoso oun logun ju lọ lọdun tuntun 2021 ta a ṣẹṣẹ mu yii.

Ninu iṣẹ ikini ọdun tuntun naa lo ti ṣeleri fawọn olugbe Eko lori atẹ ayelujara ẹ, o ni loootọ, manigbagbe lọdun 2021 laaye ara ẹ, tori ipenija tawọn koju lọdun naa pọ, o si fẹrẹ sun-un-yan kan ogiri, ṣugbọn ki i ṣe oun tabi ilu Eko nikan lọrọ naa ba, gbogbo aye ni.

Ṣugbọn ni bayii, ta a ti bọ sinu ọdun mi-in, o ni ohun to kan ni lati tete bẹrẹ iṣẹ lakọtun, ki ileri tawọn ṣe lati mu igba ọtun wa faraalu le wa si imuṣẹ.

‘’Gẹgẹ bii gomina yin, mo fi ara mi jin fun iṣẹ lati jẹ aṣaaju to n pese idari to nitumọ, ki n si ri i pe iṣejọba wa mu igbe aye to sunwọn ba awọn olugbe Eko. A maa ṣiṣẹ lati pese awọn nnkan amayedẹrun ati dukia pupọ si i faraalu, eyi to maa jẹ ki ọrọ-aje tubọ rọju kawọn eeyan si le gbọ bukaata wọn pẹlu irọrun.

O parọwa pe kawọn eeyan duro ti ijọba oun, ki wọn si ṣatilẹyin foun, kawọn le ṣaṣeyọri, o si ki gbogbo olugbe Eko ku amojuba ọdun tuntun naa.

Leave a Reply