Sanwo-Olu ṣeleri iranlọwọ fawọn olugbe ile ti ẹlikọpita ja si l’Ekoo

Faith Adebọla

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ pe ki ajọ ti n ri si bi ile ṣe duro daadaa si l’Ekoo, LASBCA, bẹrẹ ayẹwo sawọn ile to wa ni agbegbe ibi ti baalu agberapaa (hẹlikọpita) ja bọ si n’Ikẹja, lati mọ boya awọn ile naa ṣi ṣee lo fawọn to n gbe ibẹ abi wọn ti di ẹgẹrẹmiti. Bẹẹ lo ṣeleri iranlọwọ fawọn olugbe ile naa.

Ọṣan ọjọ Abamẹta, Satide, ni gomina sọrọ naa nigba toun ati ikọ rẹ ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ yii lati wo bi nnkan ọhun ṣe ri. Gomina Sanwo-Olu ni o pọn dandan ki ijọba wo iduro ile to wa ni Ojule kẹrinla ati ikẹrindinlogun, ọna Salvation, ni Ọpẹbi, atawọn ile mi-in to wa layiika pẹlu, tori iṣẹlẹ naa le ti mu ki awọn ile naa wa ninu ewu.

Yatọ si ti ayẹwo yii, Gomina Sanwo-Olu ni ijọba oun yoo nawo to ba yẹ lati fi ṣatunṣe si awọn ibi ti baaluu naa ti ba nnkan jẹ lara awọn ile ọhun.

O waa ba mọlẹbi awọn mẹta to doloogbe ninu ijamba naa kẹdun, o si gbadura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu fun iku airotẹlẹ to mu eeyan wọn lọ.

Gomina tun ba awọn olugbe ile ti hẹlikọpita naa ja si sọrọ, o ki wọn ku ewu, o si ṣeleri pe ijọba yoo ṣeranwọ fun wọn lori ohunkohun ti wọn ba padanu lasiko ijamba to waye ọhun.

O kere tan, eeyan mẹta, ti ẹni to tukọ naa wa lara wọn, lo dagbere faye lai ro tẹlẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja naa, latari ijamba hẹlikọpita to ja bọ sinu ọgba ile alaja kan naa.

Leave a Reply