Faith Adebọla, Eko
Ṣe ẹ ranti Jumọkẹ Oyeleke, ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ti wọn laṣita ibọn awọn ọlọpaa lo da ẹmi ẹ legbodo lọjọ Satide, ọjọ kẹta, oṣu keje, ọdun yii, lasiko iwọde ‘Yoruba Nation’ tawọn eeyan Sunday Igboho ṣe l’Ọjọta, l’Ekoo.
Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti dẹrin-in pẹẹkẹ iya oloogbe naa, Abilekọ Ifẹoluwa Oyeleke, o fun un ni ile fulaati oniyara meji ninu ọkan lara awọn ile ijọba ti wọn kọ si Irawọ, lagbegbe Ikorodu, o si tun fi ẹbun miliọnu kan naira tẹ ẹ nidii. Ki i ṣe ile ṣakala nikan o, gbogbo nnkan eelo ile bii firiiji, ẹrọ amuletutu, gaasi idana, tẹlifiṣan, bẹẹdi, aga, tabili ati bẹẹ bẹẹ lọ lo wa ninu rẹ.
Oluranlọwọ pataki si gomina, Abilekọ Titi Oṣhodi ni gomina ran sawọn mọlẹbi oloogbe naa lọjọ Abamẹta, Satide yii, ni ile pako ti wọn n gbe l’Ojule kọkandinlọgọta, Opopona Bayọ Ọṣinọwọ, Ogudu, Ọjọta, nipinlẹ Eko.
Lasiko to n fa kọkọrọ ile wọn tuntun ati sọwe-dowo miliọnu kan naira naa le Iya Jumọkẹ lọwọ, o ni ijọba ipinlẹ Eko kẹdun pẹlu wọn lori iṣẹlẹ ibanujẹ naa, wọn si fẹ ki idile naa bẹrẹ igbe aye ọtun lẹyin ijamba ọhun.
Oshodi ni: “Latigba tiṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, a ti waa wo ipo ti obi oloogbe naa ati awọn aburo ẹ wa, a si n ronu lori bi a ṣe le ran wọn lọwọ. Gomina ẹlẹyinju aanu ta a ni, Babajide Sanwo-Olu, lo ṣeto ẹbun yii ki wọn le bẹrẹ igbe aye ọtun.
Loootọ ni a ko le ji ẹni to ti ku pada saye, ṣugbọn ijọba fẹ ki igbesi aye awọn toloogbe naa fi silẹ sẹyin rọju, ko si rọrun, lẹyin iṣẹlẹ yii, ki ẹdun ọkan wọn le dinku jọjọ, tori niṣe ni ibanujẹ maa n sọ ori agba kodo.”
Iya Jumọkẹ naa ko le pa ayọ ati iyalẹnu rẹ mọra, o dupẹ, o tọpẹ da, lọwọ Ọlọrun ati lọwọ ijọba ipinlẹ Eko pe wọn ko gbagbe oun, wọn o si da oun da bukaata oun.
O ni iṣẹ ọmọọdọ loun n fi arugbo ara ṣe lati le gbọ bukaata lori awọn ọmọ mẹrin t’Eledua fi ta oun lọrẹ, Jumọkẹ ti wọn da ẹmi ẹ legbodo naa si ni akọbi oun.
‘‘Mo dupẹ gidigidi lọwọ ijọba ipinlẹ Eko pe wọn ranti emi atawọn ọmọ mi o. Ọlọrun aa bukun Gomina Sanwo-Olu, ko ni i fi iru eyi ṣẹsan fun wọn o. Gbogbo erongba ọkan wọn pata l’Ọlọrun Ọba maa mu ṣẹ fun wọn. Wọn ṣeun gidigidi, mo moore o.
‘‘Ẹ jọọ, mo fẹ ki wọn ba mi wa’ṣẹ. Iṣẹ alagbafọ, iṣẹ agbalẹ, ati ọmọọdọ ni mo n ṣe kaakiri. Atigba ti wọn ti ta ile ta a rẹnti lo ti jẹ pe ile pako yii ti ara ṣọọṣi wa kan fi ṣe wa laaanu la n gbe, ibẹ lawa maraarun n sun, ki Jumọkẹ too jade laye. Iṣẹ ti mo si n ṣe ko to lati ran awọn ọmọ mi niwee.”
Obinrin naa ni oun maa fi owo tijọba fi ta oun lọrẹ naa bẹrẹ okoowo ounjẹ tita, o loun maa maa ta irẹsi ati ẹwa.
Bakan naa lọkan lara awọn aburo oloogbe naa, Ayọmide Adeẹkọ, dupẹ lọwọ ijọba Eko, o ni ti wọn ba le ba iya oun wa iṣẹ gidi, aa le ran awọn niwee, tori oun fẹẹ wọ fasiti lọdun to n bọ.