Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti rọ awọn ọdọ ipinlẹ Eko lati dara pọ mọ ileeṣẹ ologun ati ọlọpaa.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni gomina sọrọ ọhun di mimọ n’Ikẹja, lasiko ti wọn n ṣeto ilanilọyẹ fawọn ọdọ lati wọ iṣẹ ologun ati ọlọpaa, ati lati ṣi awọn eeyan niye nipa awọn afiniṣowo-ẹru.
Ọgbẹni Olugbenga Oyerinde, ti i ṣe kọmiṣanna fun iṣẹ akanṣe sọ pe iwadii ati akọsilẹ ti fi han pe awọn ọdọ ko fi bẹẹ dara pọ mọ iṣẹ ologun ati ọlọpaa bii ti tẹlẹ mọ.
“Gbogbo awọn nnkan to n ṣẹlẹ laipẹ yii nilẹ Naijiria ti fidi ta a fi gbọdọ maa ba awọn ọdọ wa sọrọ, ka a si maa tọ wọn sọna lori igbesẹ to yẹ ni gbigbe han, paapaa ju lọ, lori iru iṣẹ ti wọn fẹẹ yan ṣe ati iru igbesi aye ti wọn fẹẹ gbe, nitori bẹẹ ni a si ṣe gbe eto ilanilọyẹ yii kalẹ.
“Akọsilẹ ti fihan pe bi awọn ọdọ wa ṣe n wọnu iṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu ati ti ọlọpaa ti dinku jọjọ, nitori bẹẹ si ni wọn ṣe n la wọn lọyẹ lati dara pọ mọ iṣẹ ọmọ ogun ofurufu ati ọlọpaa.
Awọn ọmọ Eko ni lati mọ oniruuru anfaani to wa ninu ki wọn darapọ mọ iṣẹ ologun, eyi ti ipejọpọ wa yii da le lori.
“Lọwọlọwọ bayii, oriṣiiriṣii adojukọ ni awọn ọdọ wa n ni lojoojumọ. Dida awọn ọdọ lẹkọọ lori idi ti wọn fi gbọdọ darapọ mọ iṣẹ ologun ṣe pataki lojuna ati le daabo bo orile-ede wa, bẹẹ lawọn nnkan anfaani mi-in wa nilẹ ti wọn yoo maa fi han wọn gẹgẹ bi eto yii ba ṣe n lọ”.
O fi kun ọrọ rẹ pe lara nnkan tawọn ọdọ n dojukọ nisinyii ni airiṣẹ ṣe, bi wọn ko ṣe lanfaani si eto ẹyawo fun okoowo keekeeke ati aini iriri awọn iṣẹ kan.