Sanwo-Olu kede iwosan ọfẹ fawọn opo ati arugbo l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Idunnu ṣubu lu ayọ fawọn opo ati arugbo to n gbe nipinlẹ Eko pẹlu bi Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣe buwọ lu u pe kawọn ileewosan ijọba bẹrẹ si i pese iwosan ọfẹ fun wọn lẹyẹ-o-sọka.

Iyawo gomina ọhun, Dokita Ibijọke Sanwo-Olu, lo kede ọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, nibi ayẹyẹ ayajọ eto ilera kari aye ti ọdun yii (2020 Universal Healthcare Coverage (UHC) Day)  eyi to waye nile ijọba, Alausa, Ikẹja.

O ni bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn alaini, opo, alaabọ-ara atawọn arugbo ni wọn ti wa labẹ eto ma-da-mi-dofo lori ọrọ ilera, eyi ti ijọba Eko gbe kalẹ lọdun diẹ sẹyin, sibẹ, o han kedere pe ko rọrun fawọn kan lara wọn lati maa sanwo asansilẹ ibanigbofo to yẹ ki wọn maa san, tori ika o dọgba.

Idi niyi tijọba fi mu lara ele ori owo ibanigbofo naa, lati fi pese ilera ọfẹ fawọn ti nnkan o rọrun fun lara awọn opo ati arugbo to wa nipinlẹ Eko.

Ibijọkẹ, ẹni ti Akọwe agba lẹka eto ilera ipinlẹ Eko, Dokita Bọla Balogun, ṣoju fun, sọ pe ọdọọdun ni ayajọ eto ilera kari aye yii maa n waye, ṣugbọn tọdun yii bọ soju ẹ gan-an tori ipenija arun aṣekupani koronafairọọsi to ko ṣibaṣibo ba gbogbo aye lọdun yii, jẹ ara idi ti eto ilera to gbopọn fi ni lati wa fun gbogbo eeyan.

Leave a Reply