Sanwo-Olu kede wiwọ BRT lọfẹẹ lasiko Keresi ati ọdun tuntun l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Irọrun ni lilọ bibọ maa ja si fawọn olugbe ipinlẹ Eko lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresi ati ọdun tuntun to n bọ yii pẹlu bi Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, ṣe kede pe ọfẹ ni ọkọ BRT yoo maa gbe awọn awọn olugbe ipinlẹ naa lọjọ mejeeji ọhun.

Atẹjade kan lati ọfiisi Ọga agba LAMATA, (Lagos Metropolitan Area Transport Authority), iyẹn ileeṣẹ to n mojuto igbokegbodo ọkọ BRT (Bus Rapid Transit) nipinlẹ Eko, Abilekọ Abimbọla Akinajo, sọ ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, pe ijọba ipinlẹ Eko fẹẹ ṣe koriya fawọn eeyan lasiko ọdun naa, tori ẹ ni wọn fi ṣeto yii.

O ni, “Gomina ipinlẹ wa gbagbọ pe ọna kan tawọn eeyan le fi gbadun ayẹyẹ ọdun Keresi yii, ki wọn si tun fidunnu wọnu ọdun 2022 to n bọ ni kijọba pese ọkọ ọfẹ fun wọn, o jẹ ara ọna lati ṣajọpin ayọ, alaafia ati ifẹ to so mọ ayẹyẹ ọdun Keresi.

“Awọn olugbe Eko gbọdọ wọnu ọdun tuntun pẹlu ipinnu ati ileri lati rin irinajo irọrun ati ifọkanbalẹ daadaa.

“Gomina ko gbagbe ileri rẹ lati ri i pe ipele akọkọ iṣẹ reluwee tipinlẹ Eko ti iṣẹ ti fẹẹ pari lori rẹ bayii, bẹrẹ ni ọdun 2022, gbogbo ọna nijọba fi n wa owo lati tete pari awọn iṣẹ ode yii, kawọn araalu le bẹrẹ si i j’adun wọn.

“A fẹ kẹyin eeyan tubọ ti ijọba yii lẹyin, tori igbaye-gbadun yin jẹ wa logun gan-an ni.

“A tun fi anfaani yii ṣi ẹyin eeyan leti lati ma ṣe tura silẹ lori ajakalẹ arun Korona o, bi ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ o ni i tan leeekanna.”

“A ki i yin ku ọdun, ẹ si ku iyedun o.”

Leave a Reply