Faith Adebọla, Eko
Ni Satide, ọjọ Abamẹta, opin ọsẹ yii, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu kede pe anfaani ti wa fun awọn ileejọsin kaakiri ipinlẹ Eko lati bẹrẹ isin wọn pada ni kikun gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe tẹlẹ ki Korona too de.
Awọn Musulumi ti ni anfaani ati maa kirun ẹẹmarun-un bi wọn ṣe maa n ki i tẹlẹ. Bẹẹ lawọn Kristẹni naa ti lanfaani lati maa ṣe awọn isin ti wọn maa n ṣe laarin ọsẹ.
O waa fi kun un pe eyi ko ni ki wọn ma tẹle aṣẹ ati ilana ti ijọba ti fi lelẹ lori didena aisan naa.