Sanwo-Olu paṣẹ pe kawọn ileejọsin di ṣiṣi lati ọjọ keje, oṣu yii, l’Ekoo

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ pe lati ọjọ keje, oṣu yii, ki awọn ileejọsin gbogbo nipinlẹ naa di ṣiṣi pada.

Ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni gomina sọrọ yii. O ni lati ọjọ Ẹti, Furaidee, awọn Musulumi lanfaani lati lọ si mọṣalaaṣi fun irun Jimọh. Bẹẹ lawọn Kristẹni naa lanfaani lati lọ si ṣọọṣi fun ijọsin lọjọ Aiku, Sannde, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu yii.

Ṣugbọn awọn alakalẹ ti wọn gbọdọ tẹle ni pe idaji, iyẹn ida aadọta ninu ọgọrun-un awọn to n jọsin nibẹ lẹẹkan tẹlẹ ni wọn gbọdọ gba laaye lati jọsin lasiko yii lẹẹkan naa.

Ọjọ Ẹti ati ọjọ Aiku yii nikan ni ijọsin gbọdọ maa waye, eyi ti gomina ni ijọba yoo ṣakiyesi bawọn eeyan ṣe tẹle aṣẹ yii si ki wọn too mọ igbesẹ to kan.

Bakan naa ni wọn gba awọn aṣiwaju ẹsin yii niyanju pe bo ba ṣee ṣe, ita gbangba tabi ibi to fẹ daadaa ti atẹgun wa lo daa lati maa ti ṣe ijọsin yii. O ni wọn le pin isin naa si ọna meji tabi ju bẹẹ lọ lati faaye gba awọn eeyan, ṣugbọn isin naa ko ti i faaye gba iṣọ oru.

Siwaju si i, gomina rọ awọn agbalagba lati ọdun marundinlaaadọrin pe ki wọn ma darapọ mọ awọn olujọsin, ki wọn jokoo sile wọn.

Yatọ si eyi, Gomina Sanwoolu ni ki gbogbo awọn ileejọsin yii pese omi, ọṣẹ ati ifọwọ to n pa kokoro ti awọn olujọsin yoo maa lo lasiko ti wọn ba wa nibẹ. Bẹẹ lo ni kawọn eeyan yago fun a n so mọran ẹni, a n bọwọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply