Sanwo-Olu pariwo: Wọn ko jẹ ki n ri Buhari ba sọrọ o

Aderounmu Kazeem

“Gbogbo iyanju mi lati ba Aarẹ Muhammed Buhari sọrọ paapaa lasiko ti ipinlẹ Eko n gbona girigiri ni ko so eso rere, wọn ko jẹ ki n ri i ba a sọrọ rara.”

Gomina Babajide Sanwo-Olu lo ṣe bayii sọrọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifiṣan kan. Ohun to sọ ni pe ẹẹmeji ọtọọtọ loun pe foonu Aarẹ Muhammed Buhari titi, ṣugbọn ti oun ko ri i ba sọrọ.

Sanwo-Olu fi kun un pe lọjọruu, Wẹsidee, loun kọkọ pe Aarẹ, ohun tawọn to gbe e si sọ foun ni pe Aarẹ Naijiria ko ti i si lọọfiisi. O ni nigba toun tun pe e lẹẹkeji, niṣe ni wọn tun sọ pe o n ṣepade pẹlu awọn igbimọ ẹ lọwọ.

O ni titi di asiko ti wọn ṣe ifọrọwanilẹnuwo foun yii, oun ko ti i ri Buhari ba sọrọ nipa wahala to n ṣẹlẹ l’Ekoo o.

Leave a Reply