Sanwo-Olu ti ṣawari awọn ọlọpaa mẹrin to paayan nibi iwọde SARS ni Surulere

Faith Adebọla, Eko

Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko ti ṣiṣọ loju awọn ọlọpaa mẹrin ti wọn fẹsun kan pe awọn ni wọn wa nidii aṣita ibọn to ṣeku pa ọkan lara awọn to n fẹhonu han nipa SARS ni Surulere, Oloogbe Ikechukwu Iloamuazor.

Orukọ awọn ọlọpaa mẹrẹẹrin ti gomina da ni: Inspẹkitọ Michael Bagou, Inspẹkitọ Etop Ekpoudom, Sajẹnti Benson Akinyẹmi ati Sajẹnti Madura Nnamdi.

Ninu ọrọ akanṣe kan ti gomina ba awọn eeyan ipinlẹ Eko sọ lori redio ati tẹlifiṣan laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni Sanwo-Olu ti tu aṣiri naa sita, o ni ijọba ti fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi mẹrẹẹrin naa, igbẹjọ si ti bẹrẹ lori ọrọ wọn ni olu ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii ilana fun ọlọpaa to ba ṣaṣemaṣe.

Tẹ o ba gbagbe, iyalẹta ọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, ni fọran fidio kan gba ori ayelujara, nibi ti wọn ti ṣafihan oku Ikechukwu, ẹni ọdun marundinlọgọta, ti ibọn ọlọpaa ba nibi iwọde wọọrọwọ tawọn ọdọ n ṣe lagbegbe Area C, ni Surulere, nipinlẹ Eko.

Yatọ si oloogbe yii, a gbọ pe aṣita ibọn awọn ọlọpaa tun pa inspẹkitọ kan nibi rogbodiyan to waye lọjọ naa, iṣẹlẹ yii lo si mu kawọn janduku kan ya bo teṣan ọlọpaa Surulere lọsan-an ọjọ yii.

Sanwo-Olu ni ijọba oun maa ri i pe idajọ ododo waye lai fakoko ṣofo lori awọn iṣẹlẹ ipaniyan wọnyi. O tun fi kun un pe oun ti ṣagbekalẹ eto ikowojọ igba miliọnu naira lati fi ṣeranwọ fawọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn lasiko iwọde to n lọ lọwọ yii.

Leave a Reply