Sanwo-Olu ti gbesẹ kuro lori ofin to de awọn ọlọja l’Ekoo, wọn le maa na an lojoojumọ bayii

Aderohunmu Kazeem

Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Kọmiṣanna fun ọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, Dokita Wale Ahmed, kede lorukọ Gomina Babajide Sanwo-Olu pe ki gbogbo awọn ọja to wa nipinlẹ Eko di ṣiṣi, ki awọn ọlọja maa ba ka-ra-ka-ta wọn lọ lojoojumọ, yatọ si bi wọn ṣe maa n pa awọn ọjọ kan jẹ tẹlẹ laarin ọsẹ.

Lasiko ti ọrọ korona n ran bii oorun nijọba paṣẹ pe ki awọn ọlọja naa ma ṣe maa ṣi lojoojumọ, ti wọn si ya awọn ọjọ kan sọtọ fun awọn to n ta ounjẹ, ati awọn ọjọ mi-in fun awọn ti wọn n ta awọn ohun eelo mi-in.

Ṣugbọn ni bayii, ijọba ti gbẹsẹ kuro lori ofin to de awọn ọlọjaa, wọn si ti paṣẹ pe ki wọn maa na an lojoojumọ gẹgẹ bo ṣe maa n waye telẹ ki korona too de.

One thought on “Sanwo-Olu ti gbesẹ kuro lori ofin to de awọn ọlọja l’Ekoo, wọn le maa na an lojoojumọ bayii

Leave a Reply