Sanwo-Olu tun gbe igbimọ mi-in dide lori abọ iwadii EndSARS, o lawọn maa ṣododo lori ẹ

Faith Adebọla, Eko

 Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ti tẹwọ gba esi iwadii ti igbimọ oluṣewadii lori ẹsun tawọn araalu fi kan ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS, eyi ti wọn gbe kalẹ lọdun to kọja, loju-ẹsẹ lo si ti yan igbimọ ẹlẹni mẹrin mi-in lati ṣe akọsilẹ to yẹ ki wọn le fẹsẹ awọn aba naa mulẹ laipẹ, tabi ki wọn sọ ọ dofin. Ọsẹ meji pere ni wọn gbọdọ fi ṣiṣẹ wọn.

Ọjọ Aje, Mọnde yii, lawọn igbimọ oluṣewadii naa, (Lagos State Judicial Panel of Inquiry on Restitution for victims of SARS related abuses and other matters), eyi ti Adajọ-fẹyinti Doris Okuwobi ṣ’alaga rẹ jabọ iṣẹ wọn fun gomina lọfiisi rẹ.

Iṣọri meji ni wọn pin abọ iwadii oloju-iwe ọọdunrun le meje naa si, apa kan da lori awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan tawọn eeyan mu wa ta ko SARS atawọn ọlọpaa lori ifiyajẹni ati titẹ ẹtọ ẹni mọlẹ ti wọn ni wọn hu sawọn, ekeji si da lori iṣẹlẹ akọlu to waye logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, lagbegbe Too-geeti Lẹkki, eyi to ṣokunfa yanpọnyanrin to ṣẹlẹ tẹle e.

Bi Sanwo-Olu ṣe n dupẹ lọwọ igbimọ oluṣewadii naa fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe, to si ṣeleri pe ijọba oun ko ni i yọ ohunkohun kuro ninu abọ iwadii naa, gbogbo aba ati imọran inu rẹ lawọn maa ṣiṣẹ le lori ni tododo, tawọn si maa pẹtu sọkan awọn ti SARS ti fiya jẹ lọna kan tabi omi-in, bẹẹ ni gomina naa kede agbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹrin kan to maa ṣiṣẹ lori abọ iwadii naa.

Kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Eko, Amofin Moyọsọrẹ Onigbanjo, ni alaga igbimọ naa.

Awọn mẹta yooku ni Kọmiṣanna lori ọrọ awọn ọdọ ati idagbasoke awujọ, Ọgbẹni Ṣẹgun Dawodu, Oluranlọwọ pataki si gomina lori ọrọ iṣẹ ode ati ipese ohun amayedẹrun, Ẹnjinnia Aramide Adeyọye, ati Akọwe agba lọfiisi awọn oṣiṣẹ ọba, Abilekọ Tọlani Oshodi.

Gomina ni kawọn igbimọ tuntun yii tete pari iṣẹ wọn ki igbimọ alakooso Eko le jokoo lori rẹ, ki iṣẹ si bẹrẹ lati ṣamulo awọn aba ti wọn ba mu wa.

Adajọ-fẹyinti Okwobi dupẹ lọwọ awọn ti wọn ba a ṣiṣẹ lasiko ijokoo wọn, ti wọn n wadii awọn ẹsun ifiyajẹni tawọn araalu mu wa, o ni igboya gidi ati aiṣemẹlẹ pẹlu ọgbọn ori ni gbogbo wọn fi ṣiṣẹ naa.

Ọkunrin naa ni aropọ miliọnu irinwo ati mẹwaa naira lawọn ni kijọba san fawọn eeyan bii aadọrin ti ẹri fidi ẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa SARS jẹbi wọn, wọn pọn wọn loju lọna aitọ.

Iwe ẹsun onilerugba din marun-un lo lawọn ri gba, mẹrinla ninu iwe ẹsun naa si da lori iṣẹlẹ too-geeti Lẹkki.

Igbimọ naa tun rọ ijọba lati ṣagbekalẹ ẹka ti yoo maa gbọ ẹjọ araalu ti wọn tẹ ẹtọ rẹ loju, paapaa to ba jẹ awọn agbofinro lo huwa aidaa si wọn.

Leave a Reply