Sanwo-Olu wọgi le sisan owo ifẹyinti fawọn gomina ati igbakeji l’Ekoo

Faith Adebola, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti kede pe iṣakoso oun ti wọgi le sisan owo ifẹyinti fawọn gomina ati igbakeji wọn to ti ṣejọba kọja nipinlẹ naa, oun si fẹ kile aṣofin Eko fọwọ si ipinnu ọhun.

Ọrọ yii wa ninu ẹbẹ ti Gomina Sanwo-Olu gbe siwaju awọn aṣofin ọhun laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii, nigba to n ka eto iṣuna ipinlẹ Eko fun ọdun 2021 to wọle de tan yii.

Gomina ni awọn iṣẹlẹ nla meji to ko ṣibaṣibo ba awọn olugbe Eko lọdun yii ti mu ko nira fun ijọba ipinlẹ naa lati pawo wọle labẹle bo ṣe yẹ, eyi si ti mu kijọba bẹrẹ si i wo awọn inawo ti wọn ṣi le so rọ na, lati le rowo na sori awọn nnkan to ṣe pataki si araalu ju lọ.

Awọn iṣẹlẹ meji ọhun ni ajakalẹ arun aṣekupani koronafairọọsi to bẹ silẹ loṣu keji, ọdun yii, ti ko si ti i lọ tan titi di ba a ṣe n sọ yii, ati yanpọnyanrin to waye latari iwọde ta ko SARS. O ni ipinlẹ Eko lo fara kaaṣa awọn iṣẹlẹ mejeeji ju lọ, ti eyi si ti ṣe ipalara pupọ fun ọrọ aje, kara-kata ati owo-ori sisan nipinlẹ naa.

O parọwa sawọn aṣofin naa lati tete wọgi le ofin owo ifẹyinti awọn gomina ana ati igbakeji wọn ọhun, kawọn le bẹrẹ si i dari owo naa sibomi-in ti yoo tubọ ṣelu lanfaani.

Leave a Reply