Sanwo-Olu yege lati dupo gomina lẹẹkan si i lorukọ APC

Faith Adebọla, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti jawe olubori nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to waye lati yan oludije funpo gomina ipinlẹ Eko lọdun 2023, wọn ti fun ọkunrin naa ni tikẹẹti ẹgbẹ wọn lati dije.
Eto idibo ti ko la oogun lọ rara ni, tori Sanwo-Olu nikan ni oludije ti igbimọ to ṣeto idibo abẹle naa, eyi ti Alaaji Ahmed Yuguda, ṣe alaga rẹ, fọwọ si lati kopa ninu eto naa, wọn lawọn oludije meji yooku ko le lanfaani lati kopa, nitori wọn ko fọwọ si wọn.
Papa iṣere Onikan Stadium, ni Mobọlaji Johnson Arena, leto naa ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.
Lati owurọ lawọn ero ti n rọ lọ sinu papa iṣere naa, awọn aṣoju ti wọn maa dibo, awọn oniroyin loriṣiiriṣii, awọn agbofinro ati awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn waa ṣe koriya fun ọga wọn.
Nigba to ku diẹ ki eto idibo naa bẹrẹ ni nnkan bii aago meji ọsan, Yuguda kede pe kidaa awọn ti wọn faṣẹ si lati kopa lawọn n ṣiṣẹ lori wọn, o lawọn meji ti wọn ko faṣẹ si lati kopa ni Wale Oluwo, to jẹ kọmiṣanna tẹlẹ l’Ekoo, ati Abdul-Ahmed Mustapha, akọwe agba kan.
Nigba to n kede esi idibo naa ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ, Yuguda ni ibo ẹgbẹrun kan o le aadọsan-an (1,170) ni Sanwo-Olu ni ninu apapọ ibo mejidinlẹgbẹfa (1,198) ti wọn di, eyi lo si fun un lẹtọọ lati kede rẹ gẹgẹ bii oludije ti APC fa kalẹ funpo gomina Eko, lọdun to n bọ.

Leave a Reply