Gomina Sanwoolu ṣabẹwo si Aṣiwaju Tinubu ni London

Faith Adebọla

O ti to ọjọ mẹta tawọn kan ti n gbe iroyin naa kiri pe Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Hammed Tinubu ti ku.

Gbogbo akitiyan agbẹnusọ rẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Tunde Rahman lati pana ọrọ yii lo ja si pabo pẹlu bi awọn kan tun ṣe n sọ pe irọ ni.

Nibi ti ina ọrọ naa ran de, obinrin kan to maa n sọrọ lori ẹrọ ayelujara jade si gbangba, o si ni oun ni ẹri lọwọ pe Tinubu ti ku.

Eyi ni awọn eeyan n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara ti akọwe iroyin Tinubu fi tun jade lọsẹ to kọja pe baba naa ko ku, bẹẹ ni ko wa nidubulẹ aisan gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kiri.

O ni o ti di gbogbo igba ti ọkunrin oloṣelu yii ba ti rin irinajo lọ si ilu oyinbo kawọn eeyan maa gbe ahesọ yii kiri pe o ti ku. O waa beere lọwọ wọn pe awọn wo gan-an ni ẹru Tinubu n ba ti wọn fi n gbe iru ahesọ yii kiri.

Ṣugbọn gbogbo okoto irọ naa ti ja bayii, ẹri si ti fi han pe irọ lawọn to sọ pe Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC naa ti ku n pa pẹlu bi Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, ṣe sabẹwo si ọkunrin naa niluu London. Tinubu wa lori ijokoo, gomina naa wa nibẹ tawọn mejeeji si jọ n sọrọ. Bẹẹ ni wọn ya fọto papọ lati fi han pe nnkan kan ko ṣe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa.

Ṣugbọn ẹnikan to ba akọroyin wa sọrọ lori ahesọ naa sọ pe loootọ ni ara gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko yii ko ya, ṣugbọn ko pọ to bi wọn ṣe n gbe e kiri, bẹẹ ni ki i ṣe pe o ti ku pẹlu bi fọto rẹ ṣe wa kaakiri ori ayelujara pẹlu gomina Eko bayii.

 

Leave a Reply