Jọkẹ Amọri
Lẹyin ọjọ mẹrinla to fun awọn to n taja ni Alaba Rago, to wa nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko, lori bo ṣe ni ọpọlọpọ nnkan ija oloro ni wọn n ko sinu ọja naa, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwolu ti yi oun pada bayii o, o ti tun ni ki awon eeyan naa, ti ọpọlọpọ wọn jẹ Hausa-Fulani maa ba ọrọ aje wọn lọ titi ti awọn yoo fi fẹnu ko lori ọna ti wọn yoo gba ati igbesẹ ti wọn yoo gbe lori kikọ ọja naa.
ALAROYE gbọ pe igbesẹ yii waye lẹyin ti ọba awọn Fulani nipinlẹ Eko, to tun jẹ alaga gbogbo awọn oloye Fulani kaakiri ilẹ Yoruba, Alaaji (Dokita) Muhammed Abubakar Bambado, ṣepade pẹlu Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, lorukọ awọn to n taja ni Alaba Rago.
Ẹbẹ ti olori awọn Hausa naa bẹ la gbọ pe o mu ki Sanwoolu yi ipinnu rẹ pada, to si ni ki awọn to n taja ni Alaba Rago yii maa ba iṣẹ wọn lọ titi ti awọn yoo fi fẹnuko lori ọna ti wọn yoo gba kọ ọja naa.
Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ diẹ sẹyin ni ikọ ọlọpaa ayara ṣaṣa, (RRS) ya bo agbegbe to kun fun awọn Hausa-Fulani yii, ti wọn si sọ pe oriṣiiriṣii awọn awọn nnkan ija oloro ni wọn n ko pamọ sinu ọja naa, ati pe o jẹ ibuba tawọn ọdaran maa n sa si. Abọ ti wọn jẹ fun gomina nipa ohun ti wọn ri yii lo mu ki Sanwoolu fun awọn oniṣowo to wa ni ọja naa ni ọjọ mẹrinla pere lati kuro ninu ọja naa, o ni ijọba fẹẹ tun un kọ bii ti igbalode.
Ṣugbọn pẹlu igbeṣẹ ti gomina gbe lati fi awọn eeyan naa silẹ yii, o jọ pe awọn ọdaran yoo tun maa ba faaji wọn lọ ninu oja naa, bẹẹ ni awọn ohun to lodi sofin ti wọ n ko sibẹ naa yoo maa pọ si i.