SARS ti wọn fofin de ko sẹyin mi-  Aarẹ Buhari

Aarẹ Muhammed Buhari ti kede pe loootọ loun fọwọ si bi wọn ṣe fagi le SARS to n gbogun ti idigunjale, ati pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa naa ko gbọdọ tun ṣiṣẹ nibikibi mọ ni Naijiria.

Lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe ko si nnkan to n jẹ ẹsọ SARS mọ kaakiri Naijiria, ṣugbọn bi ọga ọlọpaa Adamu Muhammed ṣe kede ẹ yii, pupọ ninu awọn ọdọ orilẹ-ede yii ni ko gba ọrọ ọhun gbọ.

Lagbegbe kan to n jẹ Lekki, l’Ekoo, niṣe ni wọn tun ya sita lọjọ Aje, Mọnde, ti wọn si n sọ pe afi ki Aarẹ Muhammed Buhari bọ sita gbangba, ko si ṣeleri fun gbogbo ọmọ Naijiria pe, eegun ajọ SARS to n gbogun ti idigunjale ko ni i ṣẹ mọ nibikibi lorilẹ-ede yii.

Ni bayii, ileeṣẹ Aarẹ ti gbọ ẹbẹ awọn eeyan orilẹ-ede yii, Buhari si ti sọ pe ki kaluku lọọ fọkan balẹ ko ni i si nnkan to n jẹ SARS mọ gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ti kede ẹ lọjọ Sannde to kọja.

Loju abala abẹyẹfo, iyẹn twitter Aarẹ Buhari ni wọn kọ ọ si pe ijọba ti tu ẹka ileeṣẹ ọhun ka, bẹẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti n gbe igbesẹ lati ṣeto lori bi wọn yoo ṣe maa mojuto awọn iṣẹ ti ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọhun n ṣe tẹlẹ ko too di pe wọn fofin de wọn pe wọn ko gbọdọ ṣiṣẹ kankan mọ.

Bakan naa ni wọn ti pin awọn ọlọpaa SARS si awọn ẹka mi-in ninu iṣẹ ọlọpaa.

 

Leave a Reply