Funkẹ Adebiyi
Ọṣere tiata nni, Ọgbẹni Ojo Arowoṣafẹ tawọn eeyan mọ si Fadeyi Oloro, ko fọrọ sabẹ ahọn sọ nipa Oloogbe Pasitọ T.B Joshua. Fadeyi loun ko le ba wọn bu u rara, oju ko si ti oun lati sọ pe ọmọ ijọ Synagogue Church of all Nations (SCOAN) ni oun.
Irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2021 yii, ni Fadeyi Oloro ba akọroyin AKEDE AGBAYE sọrọ, iyẹn lẹyin to de lati ṣọọṣi Sinagọgu, nibi tawọn oṣere ẹgbẹ ẹ bii Rọnkẹ Oṣodi Oke, Fẹmi Branch ati Jumọkẹ George naa ti lọọ sọrọ iwuri nipa Pasitọ Oloogbe Temitọpẹ Joshua.
Fadeyi sọ pe, “Ọmọ ijọ Synagogue ni mi, iranlọwọ naa ni mo ba de ọdọ ẹ, Ọlọrun dẹ jẹ ko fẹran mi yatọ. Ilu Ikarẹ la ti kọkọ mọra, Arigidi Akoko to ti wa ko jinna si Ikare Akoko ti mo ti wa, lati ile la ti mọra ki n too waa pade ẹ l’Ekoo.
“Ẹ ẹ ri i pe a tun jọra wa ni, o ti fẹran mi tipẹ. Koda, ọjọ Satide to ku yẹn lo ni ki n waa pade oun fun iranlọwọ nipa ara mi ti ko ya ati owo. O ti fun mi lasiko ti mo maa waa ba a lọjọ naa, ṣugbọn ọjọ naa lo jade laye.
“ Mo maa n lọ sori oke ẹ daadaa, ta a ba wa nibẹ bayii to ba n fọwọ kan awọn eeyan, to ba de ọdọ mi, o maa maa rẹrin-in ni, o fẹran mi pupọ o. Eeyan Ọlọrun le mi mọ ọn si i o, gbogbo awọn eeyan to ba n sọ nnkan buruku nipa ẹ, tiwọn ni wọn n sọ yẹn.
Ẹni to da ileewe rẹpẹtẹ silẹ ni UK, to n ṣaanu awọn eeyan kaakiri, alaaanu ni mo mọ ọn si. Emi o fi bo pe ọmọ ijọ Synagogue ni mi, Ọlọrun kan naa ni gbogbo wa n sin, awa ta a n lọ sibẹ ko pe nnkan mi-in ju Ọlọrun lọ.
“Eeyan ni Sinagọgu, ojiṣẹ Ọlọrun ni. Isọkusọ lawọn to ba n sọ pe ki i ṣe eeyan Ọlọrun n sọ. Wọn diidi pe awa tẹ ẹ ri nibẹ ta a jẹ onitiata yẹn ni, nitori oore to n ṣe fun wa, keeyan ma dẹ ya abara-moorejẹ la ṣe lọ.
“Temitọpẹ maa n ṣadura fun mi, o tọju mi daadaa lọna alaafia nigba ti ara mi ko ya, ti mo ba tun n lọ sile, aa tun fun mi lowo. Ajọṣẹpọ ẹmi ati ẹ ti le lọgbọn ọdun. K’Ọlọrun ba mi ṣaforiji fun un, kẹyin to fi silẹ ma bajẹ. Ẹ ṣeun gan-an”
Bẹẹ ni Fadeyi Oloro wi