Ninu oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, ni ilu Saudi ti sọ pe awọn Musulumi yoo lanfaani lati maa wa fun Umrah pada lẹyin oṣu keje ti ijọba ti gbe ilẹkun ti pa.
Ni kete ti wahala arun Koronafairọọsi gbode kan ni ijọba Saudi ti tilẹkun ẹ, paapaa fun awọn to maa n wa lati orilẹ-ede mi-in kaakiri agbaye, ti gbogbo eto Hajj ati Umrah ko si waye.
Ni bayii, ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, ni eto Umrah yoo bẹrẹ pada, nibi ti eeyan bii ẹgbẹrun mẹfa yoo ti lanfani lati jọsin pẹlu eto ilana jijina sira ẹni ati pipa awọn ofin ifopin si itankalẹ arun Koronafairọọsi mọ.
Lara eto tijọba Saudi ti la silẹ ni pe, to ba di lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa yii, eeyan bii ẹgbẹrun mẹẹẹdogun ni yoo lanfaani lati jọsin, bẹẹ lanfaani yoo tun wa lati jọsin ninu Mọṣalaṣi Anọbi Muhammed.
Lọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, lawọn Musulumi kaakiri agbaye yoo lanfaani lati maa wọ orilẹ-ede ọhun wa lati waa jọsin tiwọn naa. Eeyan bii ẹgbẹrun lọna ogun ni yoo lanfaani lati maa ṣiṣẹ Umra, iyẹn Hajj kekere lojumọ.
Lọdun 2019, eeyan bii miliọnu mọkandinlogun lo ṣiṣẹ Umrah, bẹe ni ijọba Sa
Saudi si ti sọ pe latinu oṣu kọkanla ni awọn eeyan yoo ti lanfaani lati lo mọṣalaaṣi mejeeji, ti eeyan bii ẹgbẹrun lọna ọgọta yoo maa lo mejeeji lẹẹkan lojumọ titi ti rogbodiyan Korona yoo fi kasẹ nilẹ patapata.