Sẹnetọ Balogun, aburo Olubadan, fẹẹ dara pọ mọ ẹgbẹ APC

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ki i ṣe iroyin mọ pe Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ, to tun jẹ ọkan ninu awọn ogbontarigi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), Sẹnetọ Kọla Balogun, ti binu fi ẹgbẹ oṣelu ọhun silẹ. Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ bayii ni pe ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ (APC) lọkunrin naa n gbero lati dara pọ mọ bayii.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti Balogun, to jẹ aburo Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun, ti gbiyanju lati dupo sẹnetọ lẹẹkeji lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn ti ko ri tikẹẹti ẹgbẹ ọhun gba, to jẹ pe baba oṣelu lati ilu Ọyọ nni, Oloye Bisi Ilaka, ni kinni naa ja mọ lọwọ.
Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, pẹlu awọn oloṣelu mi-in ni wọn jọ figagbaga fun ipo sẹnetọ lati ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba ilẹ yii niluu Abuja lọdun 2019, ṣugbọn to jẹ pe Sẹnetọ Balogun lo jawe olubori ninu idibo naa. Oun nikan si lọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to wọle idibo Sẹnetọ ninu awọn mẹtẹẹta to n ṣoju ipinlẹ Ọyọ, nigba ti awọn meji yooku jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣugbọn lọjọ ọdun Itunu Aawẹ, iyẹn, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu karun-un, ọdun 2022 yii, ni lẹta ti agba oṣelu to ti ṣe kọmiṣanna feto ọrọ aje lasiko iṣejọba Adebayọ Alao-Akala yii fi ranṣẹ si ẹgbẹ PDP pe oun ko ṣẹgbẹ wọn mọ lu jade si awọn oniroyin lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta ọhun, eyi ti Ọgbẹni Dapọ Falade ti i ṣe akọwe iroyin rẹ fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, o ni “emi Sẹnetọ, Dokita Kọla Balogun, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ yii, fi asiko yii kede pe lati oni, ọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu Kẹrin, ọdun 2022 lọ, mi o ṣẹgbẹ oṣelu PDP mọ.
“Mo dupẹ fun anfaani ti ẹgbẹ yii fun mi lati sin ẹkun idibo mi gẹgẹ bii sẹnetọ lati ọdun 2019 titi dasiko yii. Mo si gbadura pe Ọlọrun yoo ṣe ọna ẹgbẹ yii ni rere.”

Bo tilẹ jẹ pe Balogun ko ti i kede inu ẹgbẹ oṣelu tuntun to n lọ, ALAROYE gbọ pe aburo Olubadan yii ti n ba awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC ṣepade abẹlẹ lati ri i pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ọhun titi ọjọ meloo kan sasiko yii.

Leave a Reply