Sẹnetọ Biyi Durojaiye ti ku o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Sẹnetọ Biyi Durojaye, ẹni to ṣoju ẹkun Ila-Oorun ipinlẹ Ogun nileegbimọ aṣofin agba lọdun 1999 ti jade laye.

Ọjo Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹjọ yii, ni baba naa dagbere faye lẹni ọdun mejidinlaaadọrun-un (88).

Ilu Eko ni ọkunrin oloṣelu pataki yii ti dagbere faye lẹyin aisan ranpẹ.

Sẹnetọ Biyi Durojaye ti figba kan jẹ alaga awọn kọmiṣanna lẹka eto ibara-ẹni-sọrọ ni Naijiria (Nigerian Communications Commission).

Ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy(AD) lo ti dije dupo to fi di sẹnetọ ni 1999.

Ọjọ Oloogbe Biyi Durojaye ti pẹ ninu oṣelu Naijiria, ko too ṣiwọ iṣẹ lẹni ọdun mejidinlaaadọrun-un.

Leave a Reply