Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore fẹẹ dupo Akọwe apapọ ẹgbẹ APC

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọsun to tun ti figba kan jẹ sẹnetọ, to si ti dije dupo gomina nigba kan, Dokita Iyiọla Omiṣore, ti fi erongba rẹ lati dije dupo Akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko eto idibo gbogbogboo ti yoo waye ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta yii han.

Ninu atẹjade kan ti ọkunrin naa fi sita niluu Oṣogbo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lo ti fi ipinnu rẹ han, to si jẹ ko di mimọ pe oun ti gba fọọmu, bẹẹ  loun si ti da a pada si olu ile ẹgbẹ naa niluu Abuja lẹyin ti oun fọwọ si i tan.

Lara afojusun rẹ to fi fẹẹ dupo Akọwe apapọ ẹgbẹ naa ni lati da ohun gbogbo pada si daadaa nile ẹgbẹ yii, lati ri i pe ijọba awa-ara wa n tẹsiwaju, ki ohun gbogbo si le maa lọ bo se tọ ati bo ṣe yẹ ninu ẹgbẹ naa ati laarin awọn oloye ẹgbẹ.

Lati gbe eto to daa kalẹ lọna igbalode lati maa tukọ ẹgbẹ naa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply