Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Akurẹ ti fagi le ẹjọ ti sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo nileegbimọ aṣofin agba l’Abuja lọwọlọwọ, Nicholas Tofowomọ, pe ta ko esi idibo abẹle ti wọn di ninu oṣu Karun-un, ọdun 2022 yii, ninu eyi ti igbakeji gomina ana, Agboọla Ajayi, ti jawe olubori.
Onidaajọ Rilwanu Aikawa ninu idajọ rẹ nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, yii ni oun da ẹjọ sẹnetọ ọmọ bibi Ilẹ-Oluji ọhun nu nitori pe asiko to ṣẹṣẹ gbe igbesẹ ati pẹjọ ta ko esi idibo naa ti kọja aaye ọjọ mẹrinla ti ofin faaye gba ni ibamu pẹlu iwe ofin to de eto idibo ti ọdun 1999.
Tofowomọ yii ni wọn dibo yan gẹgẹ bii aṣofin lati ṣoju awọn eeyan ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko idibo gbogbogboo to waye lọdun 2019.
Kayeefi lo jẹ fawọn eeyan, paapaa awọn to jẹ alatilẹyin kọmiṣanna feto irinna nigba kan ri ọhun nigba to fidi rẹmi ninu eto idibo abẹle ti wọn di, ibo mẹrinlelaaadọrin (74) lo ni, ti Agboọla Àjayi to ṣẹṣẹ n darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP nigba naa si ni ibo mejidinlọgọrin (78).
Iṣẹlẹ yii lo mu ki Tofowomọ gba ile-ẹjọ lọ nipasẹ agbẹjọro rẹ, Amofin Fẹmi Emodamori, lati pẹjọ ta ko bi awọn to ṣeto idibo naa ṣe kede Agboọla gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke.
Tofowomọ ko kuku pẹjọ ta ko bi wọn ṣe ṣeto idibo ọhun gan-an, Agboọla Ajayi ti wọn kede orukọ rẹ pe oun lo jawe olubori lo pe lẹjọ, to si ni adajọ gbọdọ fagi le yiyan ti wọn dibo yan an latari iwe-ẹri ti ko kunju oṣuwọn to fẹẹ fi dije.
Kiakia ni Amofin agba Kayọde Ọlatoke to jẹ agbẹjọro Agboọla naa ti sare fun un lesi pe ẹsun ti wọn fi kan onibaara oun ko lẹsẹ nilẹ rara, niwọn igba ti alakooso ileewe ibi to ti ṣe idanwo aṣekagba ọhun ti kọkọ lọọ bura nile-ẹjọ lọdun 2006 lori asiṣe ti wọn ṣe si ọjọ ibi rẹ ti wọn kọ sinu esi idanwo Waẹẹki rẹ. Bakan ni agbẹjọro ọhun ni asiko ti Tofowomọ ṣẹṣẹ n pẹjọ ti kọja igba ati aaye ti ofin la kalẹ.
Aroyamjiyan yii lo ṣokunfa bi Onidaajọ Aikawa ṣe wọgi le ẹjọ naa lori pe awọn ẹsun ti wọn fi kan Agboọla ko lẹsẹ nilẹ.
Nigba to n fesi si idajọ naa, Tofowomọ ni ko si siṣe, ko si aiṣe, oun gbọdọ pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori idajọ naa.