Seriki awọn Hausa n’Ibadan ti ku o

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọba awọn Hausa iyẹn Sarikin Huasawa ilu Ibadan Ṣaṣa, Alaaji Ahmed Dahiru Zungeeu, ti jade laye.

Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo jade laye laafin rẹ lagbegbe Ṣáṣá, nigboro Ibadan.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin ni Zungeru, kọlọjọ too de.

Sarkin Hausasawa jẹ olori awọn Hausa niluu naa.

Aago meji ọsan ọjọ Aje ni wọn  yoo sin in nilana isinku awọn Musulumi.

Leave a Reply