Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Arakunrin kan, Idris Shuaib, ẹni ọdun mejilelogun, ti agboole Wooro, niluu Gwanara, ijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, pokunso tori pe kole jẹran sunkunsi lara obinrin.
Ẹgbọn oloogbe naa ṣalaye pe Shuaib jade nile lowurọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee, pe oun n lọ si oko baba oun bo ṣe maa n lọ lojoojumọ, laimọ pe o fẹ lọọ para rẹ ni. Nigba to debẹ lo pokunso nibi igi kaṣu to wa ninu oko ọhun.
Agbẹnusọ ajọ NSCDC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin niluu Ilọrin ṣalaye pe ṣe ni oloogbe naa pokunso sinu oko baba rẹ to wa ni Opopona Gwanara-Munduro, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, nitori ti ko le ba obinrin ni ibalopọ.
Baba oloogbe naa, Mallam Muhammad Idris, sọ pe Shuaib kẹkọọ jade nileewe olukọ agba Muydeen, to wa ni Gwanara (Muydeen College of Education, Gwanara Campus), o lo ti n gbinyanju lati para ẹ, ọjọ ti pẹ, ko too di pe o pokunso bayii.
Afọlabi sọ pe wọn ti gbe oku arakunrin naa lọ si ileewosan fun ayẹwo, iwadii yoo si maa tẹsiwaju.