Sifu difẹnsi mu ogbologboo adigunjale meji n’llọrin 

Akolo ileeṣẹ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi (Nigeria Security and Civil Defence Corps), ẹka tipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi ogbologboo adigunjale meji kan, Garuba Kabir, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati Nasir Raheem, ẹni ọgbọn ọdun, wa bayii. Ẹsun idigunjale ni wọn fi kan wọn.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ naa ni Kwara, ASC Ayọọla Michael Shọla, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lo ti ṣalaye pe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu yii, lọwọ tẹ awọn afurasi adigunjale naa lagbegbe Apálará, niluu Ilọrin, nipinlẹ naa, lẹyin ti awọn olugbe agbegbe ọhun ti wọn n ja ṣọọbu wọn mu ẹsun wa si ọfiisi awọn.

O tẹsiwaju pe awọn to mu ẹsun awọn afurasi naa wa sọ pe awọn adigunjale yii maa n fọ ṣọọbu loju ọna to lọ si Fasiti Ali-Hikmat, agbegbe New Yidi Road, ati Irewọlédé, niluu Ilọrin, ti wọn si n ko ọpọlọpọ dukia lọ lawọn ṣọọbu ọhun. Iwa to lodi sofin ti wọn n hu yii ti mu ki awọn ontaja lawọn agbegbe naa padanu ọkẹ aimọye miliọnu Naira dukia ṣọwọ wọn.

O ni lẹyin iwadii lọwọ tẹ awọn afurasi mejeeji, ti wọn si gba oniruuru awọn ẹru ti wọn ji ko bii ounjẹ, eroja foonu, alupupu, Plasma TV ati awọn ina sola loriṣiiriṣii.

Adari ajọ naa ni Kwara, Dokita Umar J.G Mohammed, ni awọn ti ṣetan lati ri i daju pe iwa ọdaran di ohun igbagbe lawujọ, o waa rọ gbogbo olugbe Kwara ki wọn maa kan si ọfiisi ajọ naa nigbakuugba ti wọn ba kẹẹfin iwa ọdaran lagbegbe wọn.

O ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, awọn afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply