Sifu difẹnsi ti mu Mufu ati ọrẹ ẹ ti wọn n dibọn bii babalawo lati lu awọn eeyan ni jibiti

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alakooso ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ọṣun, Emmanuel Ocheja, ti ṣafihan awọn ọdọmọkunrin meji ti ọwọ tẹ lori ẹsun jibiti lilu.

Awọn afurasi ọhun ni Mufutau Adeyẹmọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Ọladiji Hezekiah, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Ocheja ṣalaye nigba to n ṣafihan wọn lolu ileeṣẹ ajọ naa niluu Oṣogbo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa niluu Ileefẹ ni wọn ri awọn afurasi naa mu.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ṣe ni wọn maa n fi kaadi ipe ranṣẹ sori foonu ẹni ti wọn ba fẹẹ lu ni jibiti, wọn aa wa pe e lati sọ fun un pe ko ba awọn da kaadi naa pada.

O ni ti ẹni naa ba ti da kaadi ipe pada tan ni wọn aa sọ fun un pe baba awọn to jẹ babalawo fẹẹ fi ẹmi imoore han si i, nipasẹ bẹẹ, wọn aa bẹrẹ ọgbọn lati lu ẹni naa ni jibiti.

O fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin ọpọlọpọ iwadi ijinlẹ ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa, ti wọn si jẹwọ pe loootọ lawọn huwa naa.

Ocheja sọ siwaju pe laipẹ ni awọn mejeeji yoo foju bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply