Sodiq yii yoo pẹ lẹwọn o, ayalegbe ẹgbẹ ẹ lo gun lọbẹ laya l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti taari ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Sodiq Okunọla, lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lori ẹsun pe o gun Dauda Abdulgafar lọbẹ laya.

Inu ile kan naa ni Sodiq ati olupẹjọ, Dauda Abdulgafar, n gbe lagegbe Zone D2, Fiwaṣaye Community, niluu Oṣogbo. Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni olujẹjọ sọ pe Dauda ji nnkan ninu yara oun.

Ọrọ yii ni wọn ko lọ siwaju lanlọọdu wọn ti inu fi ṣi Sodiq bi. O fa ọbẹ yọ, o si gun Dauda ni aya ati apa, bayii ni ẹjẹ bẹrẹ si i tu bii omi, awọn araadugbo ni wọn sare gbe e lọ sileewosan laaarọ ọjọ naa.

Agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Ọlayiwọla Razza, ṣalaye pe iwa to nijiya labẹ ofin iwa ọdaran orileede yii ni olujẹjọ hu.

Agbẹjọro olujẹjọ, Okobe Najite, bẹbẹ lati gba beeli rẹ, ṣugbọn agbefọba sọ pe ṣiṣe bẹẹ yoo dabaru iwadii nitori ileewosan LAUTECH ni Dauda wa to ti n gbatọju lọwọ.

Nitori idi eyi, Onidaajọ Ishọla Omiṣhade paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa lọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ keji, oṣu keji, ọdun yii, tigbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.

Leave a Reply